Omo orileede China ti won jigbe l’Ogere ti pada sile - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 1, 2017

Omo orileede China ti won jigbe l’Ogere ti pada sile


Okan awon olopaa ko bale mo rara nigba ti won gbo pe awon ajinigbe kan tun ti ji omo orileese China ti won poruko e ni Lee Xian Qiang gbe lagbegbe Ogere, ipinle Ogun lojo Monde to koja yi, toro naa si doro eni to gbe odo min in.

Lee ti won ji gbe
AWIKONKO gbo pe ipinle Kogi ni Lee ti m bo, to n si n lo silu Abeokuta, ko too di pe awon ajinigbe naa pade e lona ni nnkan bii ago marun irole, ti won si jii gbe lero wi pe yoo dowo fawon lai mo pe omi maa pada teyin wogbin won lenu.

Ko pe ti won ji Lee gbe la gbo pe iroyin ti kan si Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu, to si pase pe kawon olopaa SARS gba ise naa se, ki won si ri awon odaran naa mu.

Ohun ta a gbo ni pe ko ju wakati meje lo tasiri awon ajinigbe naa fi tu ninu akolo won ti won n sapamo sii, nibe ni won ti bawon olopaa SARS naa woya ija, ko too di pe awon marun salo, towo si te okan ninu won.

Eni towo te naa la gbo pe o ti bere sii ka boroboro fawon olopaa bayii, to si ti seleri pe oun yoo mu won lo kaakiri ibi ti won ti le ri awon to salo naa mu.

Agbenuso fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi to gbe oro naa s’AWIKONKO leti so pe awon mefa lawon ti won ji Lee gbe, sugbon tawon marun salo pelu ota ibon lara, ti ori si tako okan ninu won, eni tawon ti n foro wa lenu wo bayii.

Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti wa rawo ebe sawon araalu pe ki won tete je kawon olopaa mo bi won ba sakiyesi awon to ni apa ota ibon lara, nitori awon tawon n wa ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI