ORO SUNNUKUN PELU TAYO ADIO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 2, 2017

ORO SUNNUKUN PELU TAYO ADIO

SE OMI-INIRA LEYI NI TABI OMINIRA?

Ti Olorun ba n se rere, opolopo lo maa lero wi pe ibi ni Eledumare n se. Bee, Yoruba gbagbo wi pe Olorun ko se ibi, rere lo n se.

Sebi ni nkan bi ogota (60) odun seyin lawon agbaagba kan ni orileede yii ko ara awon jo, ti won si pinnu pe ile Naijiria ti dagba to lati da ijoba ara re se. Idunnu nla leleyi je fun gbogbo eya to wa to wa lorileede yi patapata. Ati omode, ati agba ni won fi owo sii, koda opolopo eniyan lo di ero atimole lati owo ijoba Oyinbo amunisin, amunileru nigba naa.

Ti e ko ba gbagbe, sugbon to ba se pe e ti gbagbe e je ki n ran yin leti, odomokunrin akeko kan ni odun 1953. Odomokunrin yii ni eni akoko ti o koko da a ni aba wi pe ki a gba ominira fun orileede Naijiria. A bi okunrin yii ni ojo kejilelogun osu keje odun 1923 (July 22, 1923). Nigba to di omodun mokanlelogun, o di onkowe nile itewe kan to je ti Oloogbe Omowe Nnamdi Azikwe. Odomokunrin yi lo je gege bii onkowe to kere ju lo ninu akosile iwe itan lorileeede yi. O bere ija ominira orileede yii gege bi olori akeko nigba naa, awon Oyinbo amunisin nigba naa tii mole fun esun eyi ti a ko ba pe ni ‘’aile kora eni ni ijanu” ni odun 1953.


Awon omo orileede yii fun un ni inagije “Baba Idasile Naijiria.” Okunrin yii ku ni ojo keedogun osu kejila odun 2010. Nje ta ni eni naa ti a n soro nipa re? Awon afiwe won yii ko jo t'eni meji, bi ko se ti Oloogbe Oloye Anthony Enahoro.

Ipa takuntakun ni Oloogbe Oloye Obafemi Awolowo ko nipa gbigba ominira fun orileede yii. Enikeni ko si le ko iyan Oloogbe Herbert Macaulay kere ti a ba n soro nipa awon to ja ija ominira Naijiria. Oloogbe Omowe Nnamdi Azikwe nko. Beeni itan orile yii ko le pe lai fi enu ba die ninu ipa ti Oloogbe Sir Ahmadu Bello ko ninu ija ominira yii.

Awon won yii ni won woye ojo iwaju rere fun Naijiria, sugbon e ma je ki a gbagbe pe bi awon omo orileede yii ti ni afojusun ojo ola rere, beeni awon Oyinbo amunisin naa wo ye ojo iwaju to sunwon fun un, ko daa, okan ninu awon amoye tie so pe ti ile alawo dudu kan yi o ba ta kangbo pelu orileede Europe ni ojo iwaju orileede naa yoo je Naijiria.


Ko ba dara ti a ba le menu ba die ninu afoju sun awon amoye won yii. Fun apeere; gege bi gbogbo aye ti se mo pe ise agbe ni ise ni ise wa ni Naijiria, ti Olorun si tun ti fi ile olora jinnki wa de bi wi pe ninu ise agbe, ko fee si orileede naa ti o le ta kangbon pelu Naijiria, e je kin in toka awon orileede bi Singapore, Malaysia, Brazil ati awon min in ti ise agbe ti laami laaka. Ibere mi ni wi pe nje kinni in kan n be lawon orileede wonyii ti ko si lorileede Naijiria bii?

Ko fee si ninu iwoye mi, sugbon kin ni ipo orileede yi lonii ninu ise agbe kaakiri agbaye. Ibeere ni eyi ti a si maa menu ba ni ojo iwaju.


A ko le dahun ibeere mi yii (Se Omi Inira Leyi Ni Tabi Ominira?), bi ko se pe ki n mu enu ba die ninu itan ominira orileede yii. awon wo lo fi emi won lele?, Awon wo ni won mu ominira wa?, Ki ni ipa Oloogbe Oloye Obafemi Awolowo ninu ominira Naijiria? Kin ni in o fa ogun abele? Kin ni  in ti ijoba ologun ti se je ninu oro yii? Awon wo ni apase wa? Nje eranti Oloogbe Oloye Moshood Abiola. E ma gbagbe pe eeyan takuntakun ni Oloogbe Pa Abraham Adesanya. 


E je ka pade lose to m bo
Emi omo yin 
Adio Tayo Ibrahim
[email protected]
08105088418

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI