Saburi ba moto Tunde je so pe ki Adajo ju oun sewon - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 6, 2017

Saburi ba moto Tunde je so pe ki Adajo ju oun sewon

Oro buruku toun terin nile ejo Majisireeti to wa ladugbo Isabo nilu Abeokuta lojo Fraide ose to koja yi nigba to okunrin eni odun metalelogoji (43) kan, Saburi Yusuf so fun adajo ile ejo naa pe o te oun lorun lati sewon ju koun san owo lo nitori toun ko lowo lowo.


Ohun ta a gbo ni pe lojo Abameta Satide to lo lohun, iyen ojo mejidinlogbon osu to koja la gbo pe Yusuf lo sile Tunde Olaleye to wa labule Adu nitosi OGTV, Ajebo nipinle Ogun, to si loo fo gilaasi moto naa, ti won pe ni Opel.

AWIKONKO gbo pe owo awon nkan ti Saburi ba je lara moto naa le ni egberun lona ogota (60,000) naira, eyi lo fa ti Tunde fi wo o lo siwaju Onidajo Idowu Olayinka lati fi owo muu.

Nigba to n jeri gbe ara e, Saburi so pe ibi ayeye ikomojade kan loun ti n bo lale ojo naa, toun si gbagbe sun lo segbe ona nitori toun ti muti yo, sugbon nigba toun maa laju, se ni Tunde n gba oun nipa, to si tun ja oun sihoho.


O nidi niyii toun se binu lo sile e, toun si lo fo gbogbo gilaasi moto e, nitori iwa buruku to hu soun, toun ko si mo boun se fe e gbesan pada.

Tunde loun ko mo nnkan toun le se lo je koun lo o foro naa to awon olopaa leti, ti won si ni kawon pade nile ejo.

Onidajo Olayinka leyin to ti gbo atotonu awon mejeeji, lo ba beere lowo Saburi wi pe se o setan lati san owo ti yoo fi tun moto naa se tabi ko lo fi ewon jura.


Iyalenu lo je pe adajo naa ko tii soro e de le ti Saburi ti sare gba a mo lenu wi pe oun ko ni owo toun fe e san, nitori ko si ise toun le fi ri owo naa san, nitori naa, o te oun lorun lati loo sewon ju koun san owo lo.

Tiyanu-tiyanu ladajo fi wo Saburi, to si so pe oun sun igbejo siwaju di ojo kerindinlogbon osu kinni in odun to m bo, sugbon kawon olopaa si fi Saburi pamo titi digba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI