ASIRI LANLOODU TO N JALE TU L'ABEOKUTA - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, August 22, 2018

ASIRI LANLOODU TO N JALE TU L'ABEOKUTA


Won ni bi iku ile ko ba pa ni, ti ode ko le pani, bee ni won tun n so pe ara ile eni gan an lon n se ni, awon oro yi gan an lo lo lo nibàmu pelu bowo olopaa ipinle Ogun se te Ogbeni Adegbite Toareed ti won loo lo digun ja ore e, Taiwo Raheem rl'ole.

Taoreed
Ohun ta a gbo ni pe ore timotimo ni Taoreed ati Raheem, ko da a , ile won ko jinna si ara won  ladugbo Oke-Odo, Soyoye Abeokuta.

Ni nnkan bi aago merin aaro kutu ojo Wesde ose to koja yi la gbo pe Taoreed lo gbimo papo pelu awon ore e meta kan to je pe ise adigunjale ni won n se, lati loo gba moto tuntun ti Raheem sese ra.

Oju orun la gbo pe Raheem wa tawon adigunjale naa fi wole to o, ki won to o yo ibon sii lati gba kokoro moto naa lowo e. Bi won se gba jokoro moto naa tan, ti won n gbe e lo la gbo pe Raheem ta awon olopaa Lafenwa lolobo, tawon naa si gbera lesekese.

Ko si nkan meji to n je kayeefi fawon to gbo nipa isele naa, bi ko se pe Taoreed yi gan an lo ko Raheem bi won se n wa moto, to si tun gba a nimonran pe ko loo ra moto, to ba fe dangajia daadaa.

AWIKONKO gbo pe nibi ti won ti n salo ni won ti ko sowo olopaa, ti won si yi pada lesekese. Eyi lo mu kawon olopaa naa gba tele won, nigba towo yoo si te won, agbegbe Oke-Ata lowo palaba won ti segi.

A gbo pe se ni won duro lati soju ibon ko awon olopaa, sugbon tawon yen naa ko gba fun won, toro si di boolo o yago nigba toro naa di isu ata yan an yan an.

Leyin o reyin la gbo pe ibon ba meji ninu awon tawon meji to ku si na papa bora. Nigba tile.mo daadaa ni won ranse pe Raheem lati wa a won awon adigunjale.

Iyalenu lo je fun Raheem nigba to toju kan Taoreed to je ore e. Ohun gan an lo je ka mo pe Taoreed lo ko ohun bi won se n wa moto, to si tun gba oun nimonran lati loo ra moto.

Raheem nigba to n soro so pe nigba tawon adigunjale naa dele oun, Taoreed ko so nnkan kan jade lenu kasiri e ma ba tu sita, nitori toun da ohun e mo, sugbon tesan olopaa Lafenwa loun ti rii.

Abimbola Oyeyemi nigba to n toju awon odaran naa han fawon oniroyin so pe isele naa ko je tuntun, nitori e lawon to n ba ara won se ore ko se gbodo maa fingbogbo igba fininu tan ara won.

O ni bo tile je pe awon si m wa ona tawon yoo gba rowo to awon meji to salo, sibe, ose yi gan an lawon yoo toju Taoreed ati enileji e bale ejo.


PÍN-IN KÁÀKIRI