AMUGBALẸGBẸ IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN ṢE IGBEYAWO ALARINRIN, GBOGBO AYE LO N ROYIN DASIKO YI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, August 7, 2019

AMUGBALẸGBẸ IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN ṢE IGBEYAWO ALARINRIN, GBOGBO AYE LO N ROYIN DASIKO YI


Ẹsẹ ko gba ero niluu Ekoo lopin ọsẹ to kọja yi nigba ti Omidan Kanyinsọla Fagbayi to jẹ amugbalẹgbẹ igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ Oyedele ṣe igbeyawo alarinrin, to si jẹ pe gbogbo agbaye lo peju sibẹ.

Gbọngan ayẹyẹ M2 Arẹna to gbajumọ daadaa niluu Ekoo ni ayẹyẹ naa ti waye, nibi ti mọlẹbi, ara, ọrẹ, ojulumọ atawọn ololufẹ Kanyinsọla Fagbayi ati ọkọ rẹ, Ọladoye Ọdunsi ko gba gbogbo agbegbe naa, to si jẹ pe haha ni agbegbe naa di pa.

Lara awọn ti wọn wa nibi ayẹyẹ naa ni: Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun funra rẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ Oyedele ati ọkọ rẹ, Alaaji Bọde Oyedele; Iyawo Gomina ipinlẹ Ogun, Arabinrin Bamidele Abiọdun; Olori awọn oṣiṣẹ Gomina ipinlẹ Ogun, Alaaji Shuaib Salisu; Ọnọrebu Jimọh Ojugbelẹ to n ṣoju agbegbe Ado-Odo Ọta.

Awọn min in ni Oludamọnran fun Gomina ipinlẹ Ogun lori ọrọ iroyin, Arabinrin Mọdele Ṣarafa-Yusuf; Olori awọn oṣiṣẹ ijọba, Onimọ-ẹrọ Lanre Bisiriyu; awọn akọwe agba, awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC atawọn eeyan jankan-jankan min in lawujọ ni wọn lọọ yẹ ayẹyẹ naa si i.

Nigba to n gbawọn tọkọ-tiyawo tuntun naa lamọnran, Alaga ayẹyẹ naa, Oloye Ademọla Akilẹ Shabi to pe dandan ni kawọn mejeeji jẹ ọrẹ ara wọn, ti wọn ko si gbọdọ fi nnkan pamọ funra wọn nitori pe wọn ti di ọkan ṣoṣo.

Bẹẹ lo sọ pe ki wọn ma ṣe yago fun awọn ọrẹ to le mu wọn dagba ninu ẹmi ati pe ki wọn ma ṣe gbagbe lati maa ṣaanu fawọn obi wọn ti wọn tọju wọn dagba, paapaa pẹluu ipo wọn lawujọ, nitori pe aṣiri aṣeyọri igbeyawo gidi ni.

Oni nnkan, igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun lo dari bi wọn ṣe ge akara oyinbo lọjọ naa.

Diẹ re lara awọn fọto ayẹyẹ igbeyawo naa.


No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI