LỌJỌ TI ṢỌỌṢI RIDIIMU LE AWỌN EEYAN JADE NI KAMPU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 6, 2019

LỌJỌ TI ṢỌỌṢI RIDIIMU LE AWỌN EEYAN JADE NI KAMPU

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Titi dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan lọrọ naa ṣi n jẹ kayeefi fawọn to gbọ, paapaa awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja lọ lọhun nigba ti wọn lawọn alaṣẹ ati adari ṣọọṣi Ridiimu, iyẹn The Redeemed Christian Church of God nipinlẹ Ogun digun lọọ ko awọn ọmọ ijọ naa, to si jẹ pe kaakiri igboro ilu Abẹokuta ni wọnlọọ ja wọn ju si.

Ni nnkan bi aago mejila oru la gbọ pe awọn godogodo to wa ninu ile ipagọ naa atawọn ọlọpaa inu Ridiimu naa ko ibọn, ẹgba, ti wọn si lọ n ko awọn eeyan naa ti wọn lọọ ti pe ti wọn ti n gbe inu ile ipagọ naa lai niṣẹ lọwọ wọnu mọto, pe awọn ko fẹẹ ri wọn mọ.
A gbọ pe ko din leeyan igba ti wọn ko wa sawọn agbegbe kaakiri iluu Abẹokuta. Awọn agbegbe naa ni ikorita NNPC nitosi Oke-Mọsan; Kutọ; Oke-Ṣokori; Ita-Ọṣin atawọn min in, eyi ti wọn si lawọn eeyan naa ko mọ ibi tawọn wa.

Nigba ti ariwo maa ta, ni nnkan bi aago meje aarọ tilẹ ti n mo daadaa, lawọn araalu bẹrẹ sii ri awọn eeyan naa ti wọn n sunkun lori iwa ti wọn lawọn eeyan Ridiimu naa hu si wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ahesọ to kọkọ tẹ AWIKONKO lọwọ tẹle ni pe, ṣe ni ile ipagọ Ridiimu fawọn eeyan naa ṣetutu, ti wọn si lọọ dawọn silẹ kaakiri ọna to jin ki aṣiri ma baa tu, ṣugbọn nigba ta a de ibi tawọn eeyan naa wa lagbegbe Oke-Ṣokori, ọtọ ni nnkan ti a ba.

Ẹsẹ ko gbero nibi tawọn eeyan naa wa, iyẹn awọn ero to waa woran lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ. Ohun to mu kawọn eeyan maa sọ oriṣiriṣi ni bawọn ti wọn ja silẹ naa ko ṣe tete sọrọ, ati pe imura wọn ko jọ ti eeyan gidi to mọ nnkan to n ṣe.

Ṣugbọn nigba ta a fọrọ wa wọn lẹnu wo, ni wọn jẹ ka mọ pe kii ṣe pe wọn fawọn ṣetutu, bẹẹ ni kii ṣe pe wọn lu awọn ki wọn too fagidi ko wọn wa sibẹ, ṣugbọn ṣa, ojiji to bawọn lo mu kawọn fẹẹ le ya were.

Oluwaniṣọla, to jẹ ọkan lara awọn eeyan naa sọ pe “Ọmọ ilu Ikarẹ nipinlẹ Ondo ni mi, ṣugbọn Iwo-Road n’Ibadan ni mo n gbe. Nnkan to ṣẹlẹ ni pe oju lo n dun ọkọ mi, ti wọn si ṣiṣẹ abẹ soju naa ni UCH, igba ti wọn ko ṣiṣẹ abẹ naa daadaa ni wọn tare wa si ọsibitu tiluu Eko (Eko Hospital), iyẹn ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sasiko yi.

“Ijẹta tii ṣe Mọnde ni mo gba ile ipagọ Ridiimu lọ lati lọọ gbadura. Ibi ti mo ti n gbadura niwaju Pẹpẹ (Alter) ni wọn ti wa a ba mi lojiji, pe ki n lọ wọ mọto, nigba ti mo si maa mọ nnkan to n ṣẹlẹ, mo ti ba ara mi nibi yi. Ẹ gba mi o, ko ye mi o. Mi o mọ boya wọn ti kilọ fawọn eeyan tẹlẹ toripe ibẹ kọ ni mo n gbe, bi mo ṣe wa yii, ko s’owo kankan lọwọ mi lati pada siluu Ibadan ti mo ti wa.”

Iya ọlọmọ kan toun naa kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe “Ida ọgọrin ninu ọgọrun lo jẹ pe iṣoro airi ile gbe lo gbe wa de ile ipagọ lati maa gbe, ọmọ ipinlẹ Abia ni mi, ṣugbọn Eko ni mo ngbe, ibẹ naa ni mo ti ni ipenija ile, idi ti mo fi lọ sibẹ niyẹn.

“Mo kọ lẹta si Baba Adeboye fun iranlọwọ, ṣugbọn wọn ko jẹ ki lẹta mi de ọdọ wọn. Igba to ya ni mo gbọ pe wọn n fawọn eeyan lowo pe ki wọn lọọ gba ile, iyẹn loṣu to kọja yi, ṣugbọn mi o ri gba ninu owo naa. Oṣu kejila ọdun 2018 ni mo ti wa ni Camp, mi o ni mọlẹbi, ọkọ ti mo bimọ ọwọ mi yi fun ti le mi danu. Iṣẹ awọn to n ṣa katọọnu ni mo n ṣe ni Mowe, ti mo si fi n jẹun ati ọmọ.

“Ti m ba ṣiṣẹ tan, ni maa lọ su sile ipagọ lọọ sun lalẹ. Wọn maa n sọ lawọn igba kan pe ka kuro nibẹ, ti wọn ko ba si wa le wa, a maa duro wa sibẹ, ti wọn ba le wa, ti nnkan ba si lọ silẹ, a maa tun pada lọ sibẹ, ṣugbọn eyi ti wọn ṣe yi lo buru ju, to si ya wa lẹnu, tori pe ojiji ni, ati pe awọn ti wọn wa yẹn dira wa ni.

“Bọọsi mẹfa lo tẹle ara wọn, wọn ko awọn kan gba ilu Ibadan lọ. Awọn Pasitọ kan ko awọn eeyan wọn wa lati wa a ṣe iṣọ-oru, ti wọn si pinu lati duro fun ipagọ (Congress) ti wọn fẹẹ ṣe lọjọ Fraide ati Satide yi, ti wọn a si pada ni Sande ana, gbogbo wa ni wọn ko patapata. Ti mo ba ti ri owo ile, maa pada lọ ko ẹru mi to wa nibẹ, mi o si ni debẹ mọ ti maa fi ku.

“Wọn kii jẹ ka ri Baba Adeboye, ki aṣiri wọn ma baa tu, tori pe owo ti wọn ni ki wọn pin fawọn eeyan, wọn ko pin. Wọn le fun ẹlomin in lẹgbẹrun marun tabi mẹwaa fun owo ile, ibo leeyan ti fẹẹ ri iru ile towo naa maa gba, wọn ti ko owo yẹn jẹ ni, tori pe ọpọ igba ni wọn kii fawọn eeyan lowo, ki aṣiri ma si baa tu, wọn a le awọn eeyan danu, ṣugbọn eyi ti wọn ṣe gbẹyin yi lo buru ju. Ko sibi ti mo fẹẹ lọ bi mo ṣe wa yii, tori pe ko ye mi.”

Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pe wọn n gbe ounjẹ wa fawọn eeyan naa, ti wọn si tun fun wọn lowo diẹ lati fi kuro lagbegbe naa, pada sibi ti wọn ba fẹẹ lọ.

Ọkan lara awọn ọga ọlọpaa to wa sibi iṣẹlẹ naa to b’AWIKONKO sọrọ, ẹni ta a forukọ bo laṣiri sọ pe ko si nnkan tawọn fẹẹ ṣe sii, tori pe awọn ko nibi tawọn le ko wọn lọ, dipo bẹẹ, kawọn eeyan naa wa ọna lati fi lọ sibi to ba wu wọn.

Sibẹ, ohun ta a gbọ ni pe Baba Adeboye funra rẹ ko mọ nnkankan nipa nnkan to ṣẹlẹ yi, tawọn kan si sọ pe ṣe ni wọn fẹẹ fi iwa naa ba orukọ baba naa jẹ, bẹẹ lawọn eeyan min in sọ pe ko yẹ kawọn eeyan yi lọọ fi inu ile ipagọ tawọn eeyan ti n gbadura ṣebugbe, ti wọn yoo si tun maa ṣe nnkan to wu wọn nibẹ.

Nigba to n fesi sawọn ẹsun naa lori foonu, Pasitọ Ọlaitan Olubiyi to jẹ olori lẹka eto iroyin ni ile ipagọ naa jẹ ko ye wa pe awawi lasan lawọn eeyan naa n wi, tori pe ọpọ igba lawọn ti le wọn kuro ṣugbọn ti wọn ko lọ.

Olubiyi ni, ọna lati dẹkun awọn iwa ibajẹ bii ole jija, ọbun atawọn min in lo fa igbesẹ naa, tori pe pupọ awọn alainiṣẹ lọwọ atawọn ti wọn ko nile lori lo n fi inu ọgba naa, paapaa awọn ṣọọṣi ibẹ ṣebugbe, tawọn min in si tun n jale.

Bẹẹ lo sọ pe bawọn ṣe n fun awọn ti wọn ko nile lori lowo ile ni wọn tun n pada wa, ati pe bawọn eeyan ba iranlọwọ wa, lẹsẹkẹsẹ lawọn n ṣe e fun wọn lati ma gba iwa ọdaran laaye. Bakan naa lo lawọn ṣakiyesi pe wọn ti sọ iwa naa di iṣẹ, eyi to si n ta abuku ba wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI