Baba agbalagba kan tọjọ ori ẹ ti le lọgọrin ọdun lo ti pariwo sita wi pe awọn kan wo ile toun ti n gbe inu rẹ lati bi ọdun mẹtadinlaadọta sẹyin, ati pe gbogbo ọdun marundinlogoji toun lo lẹnu iṣẹ ijọba loun fi kọ ile naa.
Alagba Fasanya Yusuf Amọda lorukọ baba yii, agbegbe Ketu n’ipinlẹ Ekoo ni ile naa si wa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ọsẹ to lọ lọhun la gbọ pe ileeṣẹ kan to jẹ ti ijọba Ekoo, Lagos State Food Security Systems and Logistics Hub and Rhema Construction Company lọ wo ile baba naa, lai sọ fun un tẹlẹ, ti wọn si da oun at’awọn mọlẹbi rẹ sita lọsan gangan.
Gẹgẹ bi baba naa ṣe ṣalaye, o sọ pe ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin loun pariwo sita wi pe awọn ajagungbalẹ kan n wa ọna lati gba dukia oun lọna aitọ, ati pe awọn oloye ilu naa tun n ṣatilẹyin f’awọn ajagungbalẹ ọhun.
Baba agba to fẹyintii lẹka ileeṣẹ ijọba apapọ gẹgẹ bi awakọ agba, Senior Motor Driver Mechanic 1 lọdun 2003 sọ pe oun ti kọwe ẹsun ranṣẹ si Gomina Babajide Sanwo-Olu lati dide iranlọwọ foun, lati dẹkun awọn ajagungbalẹ ti wọn fẹẹ gba dukia oun lọsan gangan, ṣugbọn toun ko gbọ nnkankan.
Baba naa to tun jẹ alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC l’Ekoo ninu iwe ẹsun naa sọ pe awọn oloye kan gbe awọn ajagungbalẹ dide lati foun ni gbedeke ọsẹ meji lati kuro ninu ile toun n gbe, ti wọn si tun n dunkooko koun.
Siwaju sii ni baba naa sọ pe ounlawọon iwe ẹri toun fi ra ilẹ, ati awọn iwe ẹri toun fi jẹ ojulowo ẹni to ni ilẹ ati dukia naa.
Siwaju sii ni baba naa sọ pe ounlawọon iwe ẹri toun fi ra ilẹ, ati awọn iwe ẹri toun fi jẹ ojulowo ẹni to ni ilẹ ati dukia naa.
O loun ti kọkọ lọ fi iṣẹlẹ ọhun to Ọlọja tiluu Ẹpẹ, Ọba Kamọrudeen Iṣhọla Animaṣhaun, ṣugbọn to sọ pe oloye kan, Adewale Badru lo n dina mọ oun.
O ni Oloye Badru ti figba kan sọ pe oun yoo gbe miliọnu kan kalẹ lati fi ra ile oun, ṣugbọn to sọ pe dukia oun ti wọn wo danu ko din ni miliọnu mejilelogun naira.
Bẹẹ lo rawọ ẹbẹ s’ijọba Ekoo labẹ Gomina Sanwo-Olu ati awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria lati dide iranlọwọ foun lori bi awọn ajagungbalẹ ṣe sọ oun di alainile lori lọsan gangan, ati pe abẹ afara loun n sun kaakiri, nitori ti ko si ibi toun fẹẹ lọ.
No comments:
Post a Comment