Lẹyin ti ori ko Gomina Radda yọ ninu ijamba ọkọ, ẹgbẹ gomina Naijiria ṣabẹwo sii ni Katsina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 24, 2025

Lẹyin ti ori ko Gomina Radda yọ ninu ijamba ọkọ, ẹgbẹ gomina Naijiria ṣabẹwo sii ni Katsina

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ati gbogbo gomina ilẹ Naijiria ti lọ si ipinlẹ Katsina lati ṣatilẹyin fun Gomina Dikko Umaru Radda ti ori ko yọ ninu ijamba ọkọ.

Laipẹ yii ni Gomina Radda kagbako ijamba ọkọ lopopona Katsina siluu Daura.

Lara awọn gomina to wa nibẹ ni: Abdullahi Sule tipinlẹ  Nasarawa; Hyacinth Alia tipinlẹ Benue; Biodun Oyebanji tipinlẹ Ekiti; Mohammed Umar Bago tipinlẹ  Niger; Babagana Zulum tipinlẹ Borno, ati Ahmed Usman Ododo tipinlẹ Kogi.

Awọn miran ni Nasir Idris tipinlẹ Kebbi; Ahmed Aliyu tipinlẹ Sokoto; Francis Nwifuru tipinlẹ Ebonyi; Umar Namadi tipinlẹ Jigawa; Uba Sani tipinlẹ Kaduna; Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun; Lucky Aiyedatiwa tipinlẹ Ondo; Sẹnetọ Akan Udosen Eyakenyi; igbakeji gomina ipinlẹ Akwa Ibom to ṣoju Gomina Umo Eno ati awọn miiran.

Nibi abẹwo naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe digbi lawọn wa lẹyin Gomina Radda, ati pe awọn yoo maa ṣatilẹyin fun loorekoore.

Wọn gbadura pe Ọlọrun ko nii jẹ ki aburu ṣẹlẹ sii mọ pẹlu awọn araalu naa .

Gomina ipinlẹ Imoo, Sẹnetọ Hope Uzodimma to jẹ alaga ẹgbẹ gomina lo lewaju awọn gomina naa.

Nibẹ ni wọn tun ti lo anfaani abẹwo naa lati gbadura fun aarẹ ana, Muhammadu Buhari wi pe ki Ọlọrun tẹ oku rẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI