Nko beere owo lọwọ Adelabu o - Wolii Ayodele pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 14, 2025

Nko beere owo lọwọ Adelabu o - Wolii Ayodele pariwo sita

Ogbontarigi Wolii Agbaye nni, Primate Elijah Babatunde Ayodele ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin wi pe oun fẹẹ lọ minisita feto ina, Bayo Adelabu lọwọ gba.

Wolii Ayodele to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church to wa nipinlẹ Eko lo sọrọ naa laipẹ yii, ninu atẹjade to fi sita.

Atẹjade naa ti amugbalẹgbẹ Wolii Ayodele, Ọgbẹni Oluwatosin Osho fi sita lọjọ Ẹti to kọja, jẹ ko di mimọ pe Adelabu beere iye ti wọn n ta duuru, toun si sọ pe ko ran ọkan lara awọn ọmọ ẹyin ẹ lati lọ beere.

O ni gbogbo ifẹsunkan ti wọn sọ pe oun fẹẹ lu jibiti miliọnu lọna aadọjọ naira naa kii ṣe otitọ rara.

Laipẹ yii ni Adelabu fẹsun kan Wolii Ayodele lọdọ ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS wi pe gbajumọ Wolii naa sọ pe koun ra duuru ẹgbẹrun kan, eyi ti owo rẹ jẹ aadọjọ miliọnu naira.

Minisita naa sọ pe boun ko ṣe dahun si ibeere Wolii Ayodele ko jẹ ko sọ asọtẹlẹ wi pe oun ko nii di gomina ipinlẹ Oyo.

Osho ninu atẹjade naa sọ pe duuru lasan ni Wolii Ayodele n beere lọwọ Minisita lati ra, kii ṣe pe owo lo fẹẹ gba lọwọ ẹ.

O ni funra Minisita lo beere iye ti awọn duuru naa yoo jẹ, ti Wolii si sọ fun un pe ko ran ẹnikan lati lọ beere iye ti wọn n ta a.

“Nko sọ fun Bayo Adelabu lati mu owo wa ki n le gbadura fun un, mo kan sọ fun un pe ko ran eeyan kan lati ọdọ ẹ, ko lọ beere iye ti wọn n ta duuru lọja, ati pe ẹnikan lati ọdọ mi naa yoo tẹlẹ ẹni to ran, lati le jọ lọ. Amugbalẹgbẹ rẹ, oun funra rẹ, ati ẹnikan to ran si mi ni wọn jọ n da mi laamu, nitori to n fẹ lati di gomina.”

“Oun lo ran eeyan si mi lati ba mi sọrọ. Oun naa lo tun sọ pe ko si nnkan toun ko le fi silẹ lati le di gomina ipinlẹ Oyo, to si jẹ pe oun kan ṣoṣo to le ṣe ni lati ra duuru, fun anfaani ara rẹ.”

Siwaju sii lo ni oun ṣalaye fun Adelabu pe wọn ko ni fẹẹ fun un ni tikẹẹti gomina, ṣugbọn nipa wiwa aanu Ọlọrun nipa rira awọn duuru naa, kii ṣe fun ijọ oun, ṣugbọn to kọ jalẹ. 

“Mo sọ fun un pe wọn ko ni fẹẹ fun un ni tikẹẹti gomina, ṣugbọn to ba fẹẹ gidigidi, ko wa aanu Ọlọrun nipa rira ohun elo orin fun Ọlọrun, kii tiẹ ṣe ko jẹ fun ijọ mi, ṣugbọn o sọ pe oun ko le ṣee, ko si ju bẹẹ lọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI