Iṣọkan: Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina Kwara ṣepade pẹlu awọn olori nijọba ibilẹ Irẹpọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 2, 2026

Iṣọkan: Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina Kwara ṣepade pẹlu awọn olori nijọba ibilẹ Irẹpọdun


Latile jẹ ki iṣọkan ati alaafia jọba laaarin ilu, amugbalẹgbẹ gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode, Akewejẹ Ọlayinka Michael Fafoluyi ti ṣepade pọ pẹlu awọn olori ijọ ni wọọdu
 Ipetu/Rore/Aran-Orin to wa nijọba ibilẹ Irepodun.

Akewejẹ rọ gbogbo awọn olori ijọ naa lati dide gbadura fun iṣọkan, iṣokan ati iṣerere ipinlẹ Kwara.

Fafoluyi tọpọ tun n pe ni Solace sọ pe adura nikan lo le mu ki ijọba ati ipinlẹ naa tẹsiwaju, fun igbayegbadun araalu.

O ni atilẹyin wọn nipa adura lo n jẹ ki Gomina Abdulrahman Abdulrazaq maa tẹsiwaju ninu iṣẹ idagbasoke to n mu ilọsiwaju ba ipinlẹ naa.

Akewejẹ jẹ ko di mimọ pe ipinlẹ Kwara lasiko yii nilo adura ati iranlọwọ ti ẹmi lati ọdọ awọn olori ijọ, to si ni ko tii si iṣakoso to mu ọrọ awọn olori ẹlẹsin lọkunkundun, yatọ si ti Gomina AbdulRazaq.

“Bi a ti ṣe wọnu ọdun tuntun, ipinlẹ Kwara ati orileede yii lapapọ nilo iranlọwọ gidi lati ọdọ awọn alufaa Ọlọrun.  Eleyii ṣe pataki pupọ bi a ti n sunmọ asiko eto idibo,” Fafoluyi sọ bẹẹ.

“Ẹ dakun, ẹ bẹrẹ sii gbadura fun alaafia ati iṣọkan lati bori nipinlẹ ati orileede wa. Ni iru awọn asiko bayii, awọn ẹda kan n wa ọna lati mu ifẹ ara wọn ṣẹ, paapaa nipa iwa ẹtanjẹ. Ṣugbọn ṣam nipa adura awọn baba wa, yoo dara fun ipinlẹ Kwara.”.

O wa gbe oṣuba kare fun awọn olori ijọ lori ipa ti wọn n ko lati maa ṣe igbelarugẹ fun iṣọkan ati iwa ọmọluabi lagbegbe wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI