Ileeṣẹ to n ri sọrọ epo rọbii nilẹ Naijiria, iyẹn Nigerian National Petroleum Company Limited, NNPCL, ti kede yiyọ ogun naira kuro ninu iye ti wọn n ta jaala epo
Ohun ti a gbọ ni pe kaakiri awọn agbegbe kan niluu Abuja, awọn ile-epo NNPCL ti n ta jaala ni ₦815, dipo ₦835 ti wọn n ta a tẹlẹ.
Lara awọn oṣiṣẹ NNPCL to ba omiroyin sọrọ niluu Abuja jẹ ko di mimọ pe irọlẹ ọjọ Aiku to kọja ni wọn ti bẹrẹ sii ta jaala epo ni ₦815, leyin ti wọn yọ ogun naira kuro.
Ṣugbọn ṣa, iye owo ti NNPCL n ta jaala epo rẹ bayii, ṣi lọ soke pẹlu naira mọkandinlọgọrin ti Dangote n ta tiẹ ni awọn ile-epo MRS kaakiri Naijiria.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2025 ni NNPCL yọ ọgọrin naira kuro lori jaala epo naa, to si jẹ pe latigba naa ni wọn ti n ta a ni ₦835 lẹyin ifigagbaga to waye, leyi to mu ki Dangote da epo rẹ pada si ₦699.
No comments:
Post a Comment