Wo orukọ gbogbo awọn mẹtadinlogoji ti wọn wa ninu ọkọ baalu agberapa to ja l’Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 6, 2026

Wo orukọ gbogbo awọn mẹtadinlogoji ti wọn wa ninu ọkọ baalu agberapa to ja l’Ondo


Awọn alakoso ti fi ẹkunrẹrẹ orukọ gbogbo awọn to wa ninu ọkọ baalu agberapa tii ṣe ‘helicopter’, eyi ti ja lulẹ nipinlẹ Ondo.

Ọjọ Aje, ana ani ọkọ baalu agberapa naa to jẹ ti awọn ọmọ ogun ja lulẹ, ti gbogbo awọn to wa ninu rẹ si ku.

Awọn awa-baalu ti a mọ si ‘Pilot’ mẹta lo wa ninu ọkọ baalu ọhun lasiko ijamba naa.

Ilu Benin la gbọ pe wọn ti n bọ, ti wọn si n lọ si ipinlẹ Eko, ṣugbọn to jẹ pe aarin meji ọna ni wahala ti bẹrẹ.

Squadron Leader MI Aburime, Squadron Leader AP Man-Ugweje, ati Flight Lieutenant IS Bako ni awọn to n wa baalu naa.

Warrant Officer Abubakar A. ati Corporal Uguru HC ti wọn jẹ mẹkaniiki ni awọn wọnyi.

Awọn eeyan ti wọn gbe ni: Flight Lieutenant TL Lazarus, Flight Lieutenant M Akinloye, Flying Officer I.M. Adeshina, Master Warrant Officer Onwuka F, Master Warrant Officer Matini BA, Warrant Officer Nuhu FS, Flight Sergeant James RB ati Flight Sergeant Mohammed AI.

Awọn miran ni: Sergeant Ani AE, Sergeant Izibenikien SI, Sergeant Alafuka C., Sergeant Mbadugha A.N., Lance Corporal Ugwuba FC, Lance Corporal Eledan GE, Mrs Ezeh Nneka, ati Godstmine Tarabina.

Awọn yooku ni: Joy Michael, Sunday Michael, Ukeme David ati Gideon Omotola.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI