ABIỌDUN JI MỌTO L’EKO, LO BA TA SORILEEDE BẸNIN, ỌWỌ FIJILANTE TI TẸ Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 16, 2019

ABIỌDUN JI MỌTO L’EKO, LO BA TA SORILEEDE BẸNIN, ỌWỌ FIJILANTE TI TẸ Ẹ


Boroboro lawọn ọrẹ meji kan ti wọn ko niṣẹ meji ju ole jija lọ n ka bayii nigba tọwọ awọn fijilante, iyẹn VSO tẹ wọn lọjọ Tuside ọsẹ to lọ lọhun lagbegbe Owode Yewa, ipinlẹ Ogun.

Akorede Surajudeen, ẹni ọgbọn ọdun ati Abiọdun Adelakun, ọmọdun mọkandinlọgbọn la gbọ pe ọwọ tẹ, nigba ti wọn si n ṣewadi ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Bọde, ẹni ti wọn loun lo ra mọto naa ni Bẹnin.

Ohun ta a gbọ pe o ṣakoba fun wọn ni mọto jiipu GL 4MATIC ti wọn lọọ ji gbe niluu Ajah, iyẹn l’Eko lọjọ kẹrinla oṣu keji to kọja yi, ti wọn si lọ ta a danu lẹsẹkẹsẹ sorileede Bẹnin, iyẹn Kutọnu.

Nigba taṣiri maa tu, ọga awọn fijilante tipinlẹ Ogun, VSO, Ọgbẹni Sọji Ganzallo ni wọn loo fọrọ naa to leti pe ko ba wọn wa n kan ṣe si, oun lo si ta gbogbo awọn oṣiṣẹ ẹ lolobo pe ki wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii ni kiakia.

AWIKONKO gbọ ni pe lẹsẹkẹsẹ ti olobo ti ta wọn la gbọ pe wọn ti bẹrẹ iwadii, ko da a tawọn oṣiṣẹ wọn lagbegbe Idiroko to sunmo Bẹnin naa ti bẹrẹ iwadii. AWIKONKO gbọ pe ọjọ Tuside ọsẹ to kọja laṣiri awọn ọdaran naa tu ni nnkan bi aago mẹfa kọja iṣẹju mẹẹdogun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ẹgbẹ fijilante nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Mọruf Yusuf sọ pe lẹsẹkẹsẹ tọwọ ti tẹ awọn ọdaran ni wọn ti ka gbogbo iwa buruku ọwọ wọn lai kii ṣe pe awọn dana iya fun wọn.

Ọgbẹni Mọruf sọ pe awọn eeyan naa jẹwọ pe ẹnikan to jẹ Bọde to maa n gba ẹru tawọn ba ji gbe lawọn ta a fun ni Bẹnin, ati pe ninu miliọnu meji aabọ owo Bẹnin, iyẹn cefa, miliọnu kan ataabọ (1.400.000cefa) lawọn ṣi gba lọwọ ẹ.

O wa jẹ ko ye wa pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe kawọn ko awọn ọdaran naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa Idiroko lati tẹsiwaju iwadii. Gbogbo akitiyan lati gbọ tẹnu alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi lo ja si pabo titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI