Ẹ FURA O: ỌRILEEDE BENIN NI ỌLAWALE TI N WA FI OWO LU AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA NI JIBITI AYEDERU OWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 16, 2019

Ẹ FURA O: ỌRILEEDE BENIN NI ỌLAWALE TI N WA FI OWO LU AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA NI JIBITI AYEDERU OWO

Kani kii ṣe pe awọn oṣiṣẹ ojulalakanfinsori, iyẹn Fijilante tijọba ipinlẹ Ogun, VSO ko sun asunpara ni, bo ya ọwọ wọn ko ba ma ti tẹ baale ile ẹni ọdun mọkanlelaadọta (51) kan, Ọlawale Ibrahim ti wọn sọ pe ko niṣẹ min in ju ko maa fi ayederu owo lu awọn araalu ni jibiti lọ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, orileede Benin, iyẹn Kutọnu ni wọn sọ pe Ọlawale ti n ko ayederu owo naa wọ Naijiria, lati fi lu awọn eeyan ni jibiti, ko too tun pada lọ ko min in wa.

AWIKONKO gbọ pe ọjọ Tọside ọsẹ to kọja lọ lọhun lọwọ palaba Ọlawale ti wọn nile Samuẹl, adugbo Baba Pupa, lagbegbe Sẹmẹ, Badagry niluu Eko lo n gbe. Ilu kan ti wọn n pe ni Afuyẹ nitosi Ifọnyintẹdo, Idiroko lọwọ palaba ẹ ti segi ni nnkan bi aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa.

Nigba tọwọ maa tẹ ẹ, ibi to ti n paarọ owo lọwọ laṣiri ẹ ti tu pe ayederu owo lo kun ọwọ ẹ, to si fi n lu awọn eeyan ni jibiti. Baṣiri ẹ si ẹe tu lo gbiyanju lati salọ ko too ko sọwọ awọn oṣiṣẹ Fijilante naa.

"Ẹ ṣe mi jẹjẹ, maa jẹwọ" l'orin ẹbẹ ti wọn loo mu sẸnu nigba ti okete Ẹ ko raaye boru mọ wọn lọwọ, lẹsẹkẹsẹ lo jẹwọ pe o ti pẹ toun ti wa nidi iṣẹ naa, ati pe oun ni ọga kan to n jẹ Luwe, ẹni to loo fi Kutọnu ṣebugbe.

Nigba to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ f'AWIKONKO, alukoro ẹgbẹ fijilante, Ọgbẹni Mọruf Yusuf sọ pe ẹgbẹrun kan naira lọna mẹọo ati ẹgbẹrun mẹwa cefa lọna mẹsan an (8 pieces of #1,000 note and 9 pieces of 10,000 cefa) lowo tawọn gba lọwọ ẹ loju ẹsẹ.

O wa a sọ pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe kawọn gbe Ọlawale lo teṣan ọlọpaa Idiroko lati tṣsiwaju ninu iwadi wọn. Gbogbo akitiyan lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lo ja si pabo dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI