Wolii Ayọdele fun akọwe iroyin rẹ ni mọto bọginni, o tun fi ẹbun nla t'awọn alaini l'ọrẹ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 16, 2023

Wolii Ayọdele fun akọwe iroyin rẹ ni mọto bọginni, o tun fi ẹbun nla t'awọn alaini l'ọrẹ l'Ekoo


Yoruba bọ, wọn ni 'Yin-ni-yin-ni, k'ẹni o ṣe mi-in', bẹẹ si ni wọn tun maa n sọ pe 'inu didun lo n mu koriya wa'. Awọn ọrọ yii lo lọ nibamu pẹlu bi Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ṣe fun akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ ni mọto ayọkẹlẹ bọginni.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni WOlii Ayọdele fi imọriri rẹ han si Ọṣhọ pẹlu mọto ayọkẹlẹ bọginni, to dun un wo loju.

Yatọ si Ọṣhọ, Wolii Ayọdele tun fi ẹbun ọkọ, bọọsi, kẹkẹ maruwa ati awọn ẹbun pataki miran ti owo rẹ ko din ni miliọnu marundinlọgbọn naira ta awọn eeyan lọrẹ.
 
Lara awọn to jẹ anfaani naa ni akọroyin, awọn opo, awọn alaini, to fi mọ awọn akẹkọọ lapapọ.

Eto naa to waye ninu ọgba ijọ INRI Evangelical to wa niluu Ekoo lati saami ayẹyẹ ọjọ ibi ẹ, eyi to bẹrẹ pẹlu fifi ẹbun tọrẹ f'awọn eeyan, to bẹrẹ lati ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun yii.

Lara awọn to wa nibi eto to waye lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni Aarẹ fẹgbẹ agbabọọlu orileede Naijiria, Nigeria Football Federation (NFF), Alaaji Ibrahim Gusau; alaga fun ajọ to n gbogun ti egboogi oloro, (NDLEA), General Marwa; gbajugbaja onkọrin ẹmi nni, Yinka Alaṣeyọri; Wolii Agba, Ayọ Ajewọle, to fi mọ ọpọ awọn oṣere tiata.

Fọto:
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI