Ipinlẹ Kwara le tente ninu eto iforukọsilẹ APC lẹkun aarin gbungbun Ariwa Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 27, 2026

Ipinlẹ Kwara le tente ninu eto iforukọsilẹ APC lẹkun aarin gbungbun Ariwa Naijiria


Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ipinlẹ Kwara lo n lewaju ninu eto iforukọsilẹ to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lẹkun aarin gbungbun ilẹ Naijiria.

Awọn agbaagba APC ni wọn fidi rẹ mulẹ lọjọ Iṣẹgun, lasiko abẹwo ti igbakeji alaga ẹgbẹ naa lẹkun aarin gbungbun Ariwa, Alaaji Muazu Bawa ṣe lọ sipinlẹ Kwara lọjọ Iṣẹgun.

Ori ikanni ayelujara ni eto iforukọsilẹ naa ti n lọ kaakiri ori ilẹ Naijiria.

Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti ṣeleri pe awọn yoo tubọ ṣiṣẹ lati rii pe ọpọ awọn eeyan lo forukọsilẹ lati jẹ ọmọ ẹgbẹ naa.

“Ẹ jẹ ki n ki igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu wa lẹkun aarin gbungbun Ariwa si ipinlẹ Kwara. Ẹyin lẹ n lewaju lẹkun yii. Ẹ ti ṣiṣẹ takuntakun, ati pe agbajọwọ ni,” gomina sọ bẹẹ lọjọ Aje.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI