Tinubu, AbdulRazaq gba gomina ipinlẹ Plateau wọnu APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 27, 2026

Tinubu, AbdulRazaq gba gomina ipinlẹ Plateau wọnu APC


Lonii, ọjọ Iṣẹgun ni Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ati olori awọn gomina ilẹ Naijiria, AbdulRahman AbdulRazaq gba gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Manasseh Mutfwang sinu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima lo ṣoju Aarẹ Tinubu nibi eto igbaniwọle naa.

Gbagede papa iṣere Polo to wa nilu Jos to jẹ olu-ilu Plateau ni eto igbaniwọle naa ti waye, nibi ti awọn bii Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ko ti gbẹyin.

Awọn agbaagba APC kaakiri ilẹ Naijiria ni wọn wa nibẹ pẹlu, to fi mọ alaga wọn lapapọ, Ọjọgbọn Nentawe Yilwatda.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI