Adron Homes ṣagbekalẹ anfaani ọtun lasiko aawẹ lẹnti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 4, 2026

Adron Homes ṣagbekalẹ anfaani ọtun lasiko aawẹ lẹnti


Ileeṣẹ Adron Homes ti kede awọn afaani tuntun ti yoo jẹ ki gbogbo eeyan di onile lori, ki wọn si kuro ninu ẹgbẹ ayalegbe.

Gẹgẹ bi awọn alakoso ileeṣẹ naa ṣe sọ, wọn lawọn ti yọ ida ọgbọn kuro lori gbogbo awọn dukia wọn, eyi ti yoo fun awọn onibara ni anfaani lati jẹ igbadun rẹ.

Oṣu mẹrindinlogoji (36months) ni ileeṣẹ Adron Homes sọ pe awọn onibara ni anfaani si, lati san owo dukia ti wọn ba ra, lai daamu rara.

Asiko diẹ, tii ṣe asiko aawẹ lẹnti awọn Kristẹẹni ni anfaani naa fi ṣi silẹ, gẹgẹ bi awọn alakoso naa ṣe sọ.

Anfaani naa ti wọn pe ni 'Easter Fiesta', lo wa lori gbogbo awọn dukia wọn to wa ni Eko, Ṣimawa, Ṣagamu, Atan–Ọta, Papalanto, Abẹokuta, Ibadan, Ọṣun, Ekiti, Abuja (FCT), Nasarawa, ati Niger.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI