Ipade gbogboogbo ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara yoo waye lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, March 1, 2026

Ipade gbogboogbo ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara yoo waye lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti kede pe ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2026 ni ipade gbogboogbo ipinlẹ naa yoo waye.

Gbangan Arca Santa to wa niluu Ilorin, ipinlẹ ọhun ni ipade gbogboogbo naa yoo waye, bẹrẹ lati agogo mẹwaa aarọ.

Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Alaaji Abdulwaheed Olawale Babatunde fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2026 lo ti sọ pe gbogbo aṣoju ọmọ ẹgbẹ patapata ni awọn wọọdu to wa nijọba ibilẹ mẹrindinlogun ni yoo kopa nibẹ.

Alaaji Babatunde rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati tete de, ki wọn le tete kuro, ni imurasilẹ eto idibo ọdun 2027.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI