Awon obinrin ti a ro lagbara, orileede to duro digbi: Agbekalẹ ọjọ iwaju rere nipa dukia jijogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 11, 2026

Awon obinrin ti a ro lagbara, orileede to duro digbi: Agbekalẹ ọjọ iwaju rere nipa dukia jijogun


Gẹgẹ bi gbogbo agbaye ṣe n ṣayẹyẹ ayajọ awọn obinrin kaakiri agbaye, akiyesi ti lọ si ipa pataki to jọju, eyi ti awọn obinrin n ko lati fi to inu mọlẹbi, agbegbe ati eto ọrọ aje apapọ.

Nipa ohun to kọja didi ile mu ati ṣiṣe adari ileeṣẹ, awọn obinrin naa ti n di alagbara nipa idagbasoke orileede nipa ọkan lara awọn ohun to n mu ayipada ofun nini, iyẹn jijogun dukia.

Kaakiri Naijiria, awọn obinrin naa ti n ṣe oniruuru ohun ti ko ṣee ṣe ninu okoowo, iṣakoso, imọ ẹrọ, eto ẹkọ, ati iṣẹ ọwọ.

Eyi lo mu ki ileeṣẹ Adron Homes gbe oṣuba kare fun awọn obinrin, lori ipa ribiribi ti wọn n ko lawujọ, eyi to n ro eto ọrọ aje agbaye, paapaa ti Naijiria lagbara.

Adron Homes sọ pe bi obìnrin ṣe n ko ipa to jọju ninu eto idagbasoke eto ọrọ aje, na ni wọn tun n ṣe bẹbẹ ni oniruuru ẹka bii okoowo ṣiṣẹ, idaṣẹsilẹ, anfaani ọtun ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn si lo n mu iwuri ba wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI