Ijọba ilẹ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu bi ijọba orileede Mozambique ṣe ti awọn ọmọ Naijiria mejilelogoji mọle, ti wọn lọna aitọ ni wọn gba ti awọn eeyan naa satimọle.
Alaga ajọ to n ri sọrọ awọn ọmọ Naijiria loke okun, iyẹn ajọ NiDCOMZ Abike Dabiri-Erewa lo sọrọ naa pe awọn ko nii gba bi ijọba Mozambique ṣe fẹẹ yan ọmọ Naijiria jẹ lọna aitọ.
Dabiri-Erewa wa sọ fun ijọba ilẹ naa lati tete tu awọn ọmọ Naijiria ti wọn fi sahamọ wọn silẹ, ko too pẹ ju.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Abdur-Rahman Balogun fi sita lọjọ Aiku, oni, Dabiri-Erewa jẹ ko di mimọ pe niṣe ni wọn mu awọn ọmọ Naijiria naa lọna aitọ, ti wọn ko si fi ẹsun kankan kan wọn ki wọn too gbe wọn.
“O ba ni lọkan jẹ lati gbọ wi pe awọn ọmọ Naijiria nikan ni koju si ninu ikọlu naa,” alakoso agba naa kọminu.
“Bi eyikeyi ninu awọn ti wọn mu naa ba ti tapa si ofin ilẹ Mozambique, igbesẹ to yẹ ni lati foju wọn ba ile-ẹjọ, dipo ki wọn kan ju wọn si atimọle lai beere ọrọ lọwọ wọn.”
Dabiri-Erewa ṣapejuwe bi wọn ṣe mu awọn ọmọ Naijiria naa gẹgẹ bi eyi to jẹ ikọlu s'awọn ọmọ Naijiria, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni "xenophobic".
O wa rọ awọn alaṣẹ ilẹ Mozambique lati tete tu awọn ọmọ Naijiria naa silẹ, tabi ki wọn gbe igbesẹ to yẹ labẹ ofin, nipa fifoju wọn ba ile-ẹjọ.
“Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọja ti wọn ti n ta paati ara ọkọ ni wọn ti mu awọn ọmọ Naijiria naa, nibẹ si lo ti jẹ pe awọn ọmọ Naijiria nikan ni mu ninu gbogbo awọn olokoowo to wa nibẹ, lai jẹ pe ẹsun kan wa ni pato ti wọn fi kan wọn, tabi pe ki wọn sọ idi pataki ti wọn fi ko wọn,” atẹjade ọhun sọ bẹẹ.
Atẹjade naa fi kun un pe ojulowo olugbe ilu Mozambique ni gbogbo awọn ti wọn tọwọ to, koda to tun sọ siwaju pe adajọ agba ilẹ naa ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn.
“Wọn lu gbogbo awọn tọwọ tẹ yii, wọn tun gbẹsẹ le dukia to jẹ ti wọn, ati pe pupọ ninu wọn ni ara wọn ko da, ti wọn si nilo itọju eto ilera,” Dabiri-Erewa ṣalaye.
NiDCOM ti wa sọ pe awọn orileede kaakiri agbaye gbọdọ maa bọwọ fun ẹtọ awọn ọmọ Naijiria to ba n gbe loke okun.
No comments:
Post a Comment