Ẹgbẹ awọn agbaagbaa ati alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti pe aarẹ ile igbimọ aṣofin nigba kan, Sẹnetọ Bukọla Saraki nija lati yọju sile ẹjọ, to ba kọ pe oun ko lọwọ ninu iṣẹlẹ idigunjale to waye lawọn banki niluu Ọffa lọdun bii meloo sẹyin.
Ọjọ Aje, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ni awọn agbaagba naa sọ fun Saraki pe ko tete lọ fara han nile ẹjọ, ko si wẹ ara rẹ mọ pẹlu ẹri aridaju.
Ninu atẹjade naa ti Minisita tẹlẹ feto ere idaraya lorileede Naijiria, Ọnarebu Issa Bio Ibrahim; Alaaji Usman Bibire to jẹ alaga ijọba ibilẹ Ila-oorun Ilọrin tẹlẹ ati onimọ-ẹrọ Jimoh Alao buwọ lu, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe Saraki ni ẹjọ lati jẹ.
Wọn ni dipo ki Saraki maa lo awọn akọroyin lati fi gbe iroyin ẹlẹjẹ sita, niṣe lo yẹ ko lọ sile ẹjọ lati wẹ ara rẹ mọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Wọn ni ile-ẹjọ nikan lo le sọ pe Saraki ko lẹbọ-lẹru, ati pe ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan an, kii ṣe iwe iroyin to n lo kaakiri.
Awọn agbaagba naa labẹ agboorun APC Continuity Mandate Group wa gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, lori bo ṣe lo ọkan akin lati pe ẹjọ naa lati fi tako Saraki ati gomina ana, Abdulfattah Ahmed, ati awọn miran.
"Igbesẹ akikanji ti Gomina AbdulRazaq gbe yii, yoo jẹ ki idajọ ododo f'ẹsẹ mulẹ fun awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn, ati awọn to fara kaaṣa nibi ikọlu awọn adigunjale, ti yoo si tun kọ awọn yooku to di ipo oṣelu mu, paapaa awọn to lero wi pe wọn ga ju ofin lọ lẹkọọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.
"Ẹgbẹ yii to kun fun agbaagbaa oloṣelu ati awọn olori ilu gbe oṣuba rabandẹ fun Gomina AbdulRazaq, nitori pe igbesẹ to yẹ lo gbe lati tako Ọmọwe Bukola Saraki ati Gomina tẹlẹ , Abdulfatah Ahmed lori ikọlu idigunjale banki Offa to waye lọdun 2018.
"Nigba ti a rii pe awọn kan ti n ti ọrọ oṣelu bọ ọ, nipa asiko ti wọn fi ẹsun kan Saraki, a fẹẹ jẹ ko di mimọ pe idajọ ododo gbọdọ waye lasiko to ba yẹ, lati rii pe aabo wa fun araalu.
"Gẹgẹ bi a ti sọ ṣaaju, ile ẹjọ ni ibi kan ṣoṣo ti afurasi ti le ṣalaye ara rẹ wi pe oun ko mọwọ-mẹsẹ, idi ree ti a fi gba Saraki lamọran lati lọ gbe ara rẹ lẹyin nipa ẹsun ti wọn fi kan an, dipo iwe iroyin to fi n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri."
No comments:
Post a Comment