‘Koda bi eeyan ba fẹẹ ku, mi o kii fọwọ kan ọgọrun miliọnu kan naira, owo afipamọ mi’ – Peller - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 21, 2026

‘Koda bi eeyan ba fẹẹ ku, mi o kii fọwọ kan ọgọrun miliọnu kan naira, owo afipamọ mi’ – Peller


Gbajugbaja apanilẹrin loro ayelujara, Habeeb Hamzat ti ọpọ awọn eeyan mọ si Peller ti sọ pe oun kii fọwọ kan owo afipamọ oun, koda bo ba nii ṣe pẹlu pe eeyan kan fẹẹ ku.

Peller sọ pe boun ko ba lowo lọwọ mọ rara, ti ko si nnkan toun yoo jẹ, oun ti ko ara oun nijanu lati ma ṣe fọwọ kan owo afipamọ naa.

Bakan naa lo sọ pe boun ba nilo owo ninu mọlẹbi, ti ipenija nla si wa, niṣe loun yoo ṣe suuru, titi digba ti owo miran yoo fi de.

Ọmọkunrin naa lo sọrọ yii, nigba ti ijiroro nipa ọrọ owo, afipamọ ati ikora-ẹni-nijanu lori ọrọ eto iṣuna jẹyọ laaarin oun ati oṣere ori ayelujara, Sir Balo laipẹ yii.

Ninu fọnran naa, Peller sọ nipa oju to ma fi n wo ọrọ owo, ti bo ṣe ko ara ni nijanu, toun si jẹ ko di mimọ pe bi owo oun ba ti n kọja ọgọrun kan miliọnu naira wa silẹ, loun kii gba pe oun ko lowo lọwọ 

“Mi o kii gba lati na gbogbo owo mi kọja ọgọrun kan naira wa silẹ. Koda bi eeyan kan ba fẹẹ ku ninu mọlẹbi, mi o nii fọwọ kan owo naa. Mo maa n rii daju pe owo mi ko wa silẹ kọja ọgọrun kan miliọnu naira.

“Ọpọ igba lo wa, to jẹ pe mo maa nilo owo pajawiri nigba ti ko ba si owo lọwọ mi lasiko yẹn, inu owo orin ni maa ti lọ beere fun miliọnu mẹta naira lati lo. Ṣugbọn ṣe ẹ ri ọgọrun miliọnu kan naira yẹn, nko nii debẹ rara.

“Idi ni pe bi mo ba ti fọwọ kan, eeyan maa bẹrẹ sii na owo naa niyẹn,” o ṣalaye.

Latigba ti Peller ti sọ ọrọ yii ni oniruuru awọn eeyan ti bẹrẹ ariyanjiyan lori rẹ, bi awọn kan ṣe n sọ pe iwa ti ko dara ni, bẹẹ lawọn kan sọ pe ọna to gba ko ara rẹ nijanu dara pupọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI