O pari! Tinubu fọwọ osi juwe ile fun Wale Edun ati Ahmed Dangiwa gẹgẹ bii minisita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 21, 2026

O pari! Tinubu fọwọ osi juwe ile fun Wale Edun ati Ahmed Dangiwa gẹgẹ bii minisita


Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe asiko ti to fun minisita feto ọrọ aje, Wale Edun ati minisita feto ile gbigbe ati idagbasoke igberiko nilẹ Naijiria, Ahmed Dangiwa lati pada sile wọn, nitori pe ijọba ko nilo wọn mọ.

Eyi lo wa lara igbesẹ lati ṣe atunto ninu igbimọ iṣakoso ilẹ Naijiria, iyẹn Federal Executive Council, FEC, eyi ti Aarẹ Tinubu ṣe.

Ninu atẹjade oludamọran pataki lori eto iroyin si akọwe ijọba, Yomi Odunuga fi sita, o ni iroyin naa wa ninu lẹta ti George Akume to jẹ akọwe ijọba buwọ lu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni Taiwo Oyedele lo gba ipo ọhun bayii, gẹgẹ bii minisita feto iṣuna, alakoso feto ọrọ aje.

Bakan naa lo tun yan Ọmọwe Muttaqha Darma gẹgẹ bi minisita feto ile gbigbe ati idagbasoke igberiko.

Atẹjade ọhun wa jẹ ko di mimọ pe awọn minisita naa gbọdọ ko gbogbo iwe aṣẹ ọwọ wọn silẹ fun awọn to fẹẹ gba ipo naa lọwọ wọn, lati bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.

O ni gbogbo eto gbigbe ipo naa silẹ gbọdọ pari l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2026.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI