Oniruuru ẹri aridaju o tun ti fara han niwaju ile-ẹjọ bayii, lori idigunjale ile ifowopamọ Ọffa to waye lọdun bii meloo sẹyin.
Ijọba ipinlẹ Kwara lo tun gbe ẹjọ tuntun dide lori ikọlu idigunjale to waye naa, lati tako aarẹ ile igbimọ aṣofin ilẹ Naijiria tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki, gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Abdulfatai Ahmed, ati awọn miran.
Ẹsun ti ko din ni ogun ni ijọba Kwara gbe dide lati fi tako awọn eeyan naa nipa bi wọn ṣe kopa ninu idigunjale ọhun.
Bi ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹrin, ọdun 2018 ni idigunjale naa waye ni awọn ifowopamọ kan to wa niluu Ọffa.
Lara awọn ti ijọba ipinlẹ Kwara tun fẹsun kan niwaju ile-ẹjọ ni olori awọn oṣiṣẹ gomina labẹ iṣakoso Ahmẹd, Yusuf Abdulwahab ati Alabi Olalekan, toun naa jẹ ọmọ ẹyin gomina ana naa.
Ẹjọ naa ti nọmba rẹ jẹ kWS/114C/26, eyi to ti wa nilẹ tipẹ lo waye lẹyin ti ile-ẹjọ kọtẹmilọrun fontẹ lu idajọ awọn afurasi to lọwọ ninu idigunjalẹ naa, to fi mọ Ayo Akinnibosun, ẹni to jẹwọ pe ọkan lara awọn tọọgi Sẹnetọ Saraki loun jẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ẹsun naa lo nii ṣe pẹlu igbimọ papọ, ipaniyan ati awọn miran.
Gbogbo awọn afurasi naa ni wọn yoo kawọ pọyin rojọ niwaju Onidajọ Haleemah Salman, ti ile ẹjọ giga ilu Ilọrin.
Bi ẹ ko ba gbagbe, oniruuru ẹri lo farahan nigba ti igbẹjọ awọn ọdaran naa n lọ lọwọ lọdun diẹ sẹyin, nibi ti awọn ọkọ ati awọn ẹri miran ti wọn tọpinpin de ileeṣẹ ijọba ipinlẹ naa lọdun 2018 ti jẹyọ.
Awọn ohun elo naa la gbọ pe wọn jẹ ti ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina Ahmẹd.
Bo tilẹ jẹ pe Saraki ti sọ pe oun ko mọ Akinnibosun ri, sibẹ aworan ṣafihan awọn mejeeji papọ nibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ Saraki.
Bakan naa ni Akinnibosun ati awọn ọmọ ẹyin rẹ tun kọwọrin pẹlu Saraki lọ ki awọn mọlẹbi awọn to fara kaaṣa nibi ikọlu naa.
Ọkan lara awọn afurasi naa, nigba to n sọrọ niwaju ile-ẹjọ, o ni “Olori awọn oṣiṣẹ gomina, Ọnarebu Yusuf Abdulwahab lo fun mi ni ibọn AK47 meji ti wọn ka mọ mi lọwọ, nigba to ku ọjọ kẹta ki wọn ṣeto ipade gbogboogbo ẹgbẹ.”
Eyi si wa lara awọn ẹri ti ijọba ipinlẹ Kwara fi gbe awọn afurasi naa lọ siwaju ile-ẹjọ.
O tun tẹsiwaju pe “Emi ni mo jẹ olori awọn tọọgi to n ṣiṣẹ fun Sẹnetọ Bukọla Saraki ati Gomina Ftai Ahmed. Ọpọ igba lo maa n fun mi lowo lati pin fun awọn ọmọ ẹyin mi ti a jọ n ṣiṣẹ fun un. Laipẹ yii lo fun mi ni jiipi Lexus 300, eyi ti nọmba rẹ jẹ Sẹnetọ Saraki.
“Idaji miliọnu kan naira ni owo ti Saraki fun mi gbẹyin. Mo tun ṣi mọ awọn tọọgi miran ti wọn n ṣiṣẹ fawọn oloṣelu, ti wọn ṣi ni ibọn lọwọ, to si jẹ pe Sẹnetọ Saraki lo n ran wọn niṣẹ. Alaaji Alawo, Alaaji Dona ati Alaaji Jawondo lorukọ wọn.
“Awọn ti mo darukọ yii ni wọn n ṣiṣẹ fawọn oloṣelu, ti wọn si n lo ibọn. Idi ti mo fi mọ ni pe a jọ n ṣiṣẹ pẹlu Sẹnetọ Saraki ni,” Akinnibosun sọ bẹẹ.
No comments:
Post a Comment