Ẹkun, omije, ibanujẹ lọjọ ti wọn sinku Taiwo Hassan Ogogo niluu Ilaro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 24, 2026

Ẹkun, omije, ibanujẹ lọjọ ti wọn sinku Taiwo Hassan Ogogo niluu Ilaro


Gbogbo ilu Ilaro nipinlẹ Ogun ni wọn gbalejo awọn gbajugbaja nidi iṣẹ tiata nilẹ Naijiria, paapaa ẹka ti Yoruba.

Ko sohun meji to fa a, bi ko ṣe ti eto isinku ilu mọ-ọn ka nni, Taiwo Hassan tọpọ awọn eeyan mọ si Ogogo.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni Ogogo jade laye lẹyin aisan jẹjẹrẹ ipele kẹrin, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni "State Four Cancer".

Ọsẹ diẹ sẹyin ni wọn sọ pe aisan naa jẹyọ lara Ogogo, to si lọ gba itọju nile iwosan.

Nigba ti wọn sọ pe owo itọju naa fẹẹ kọja agbara, lo mu ki gbajugbaja sẹnetọ nipinlẹ Ogun, Solomon Olamilekan Adeola tọpọ mọ si Yayi da si i, to si ṣe iranwọ owo fun itọju.

Nigba to di pe agbara awọn oniṣegun oyinbo ko fẹẹ ka itọju naa mọ, lo mu ki awọn ọmọ Ogogo figbe ta lori ayelujara lati beere fun iranlọwọ itọju.

Awọn ọmọ mejeeji sọ pe awọn ko nilo iranlọwọ owo, bi ko ṣe iranlọwọ ti yoo mu ki alaafia pipe jẹ ti baba awọn.

Ọpọ awọn ẹlẹyinju aanu ni wọn dide iranlọwọ, ṣugbọn ti ọrọ naa pada yiwọ.


Awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa Ogogo

Taiwo Hassan lorukọ rẹ, ṣugbọn Ogogo ni inagijẹ ti ọpọ awọn eeyan mọ-ọn si.

Ogogo naa lọ ni ibamu pẹlu oriki idile rẹ niluu Ilaro

Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 1959 ni wọn bi i.

Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni ko too jade laye

Ibeji ni Ogogo, ọkunrin si ni Kehinde rẹ - Baba rẹ, ati baba-baba rẹ, ibeji ni wọn 

Ọdun mọkanla ni Ogogo wa nigba to padanu baba rẹ.

Nitori owo ni Ogogo ko fi pari eto ẹkọ girama rẹ ni Gazikia College l'Ekoo.

Ko too di oṣere tiata, o ti ṣe mẹkaniiki ri ni Yaba Technical College.

Ọdun mẹtala lo fi ṣe mẹkaniiki pẹlu ileeṣẹ to n ri sọrọ omi l'Ekoo.

Ọdun 1981 lo bẹrẹ sii fi iṣẹ tiata jẹun, nigba ti ere ori itage ṣi gbayi, ti ko tii si sinima agbelewo.

Nigba to maa kọkọ farahan gẹgẹ bi oṣere ori itage, Ewi lo ke ni National Musuem to wa ni Onikan niluu Eko.

Abẹ Awo Ademola Fagbemi lo ti kọ iṣẹ tiata nigba naa, to si tun n ṣiṣẹ pẹlu ẹ.

Lẹyin ọdun mẹtala to ti n ṣiṣẹ tiata ati iṣẹ ijọba papọ, o fi iṣẹ naa silẹ lati gbajumọ iṣẹ tiata lọdun 1994.

Inu sinima agbelewo Owo Blow ni okiki rẹ ti kan, ati pe ori bẹẹdi aisan lo wa nigba naa ti wọn fi lọ pe e.

Owo Blow naa lo fi gba awọọdu THEMA lọdun 1997.

Oniruuru sinima agbelewo ni Ogogo ti kopa, to si jẹ pe bo ṣe n kopa ninu ere, naa lo tun n dari ere.


















































No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI