Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọjade nile ẹkọ girama ti Remo Secondary School Old Students Association (RSSOSA) niluu Sagamu, Aarẹ Adetola EmmanuelKing ti gbe oṣuba kare fun igbakeji rẹ, ẹka tilẹ Gẹẹsi, Ọgbẹni Damola Aiyeola lori ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun.
Aarẹ EmmanuelKing lo gbe oṣuba kare naa ninu atẹjade to fi ranṣẹ si Aiyeola.
Ninu atẹjade ọhun, Aarẹ EmmanuelKing to tun jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited to n ta ilẹ, ile ati dukia ṣapejuwe Aiyeola gẹgẹ bi alafọkansin ẹda.
Bakan naa lo tun ni eeyan pataki to ni ibẹru Ọlọrun lọkan, to si fi ara jin fun iṣẹ adari, eyi to n mu ilọsiwaju ba awọn akẹkọọ ati ile-ẹkọ to ti jade.
O wa gbadura ẹmi gigun ati alaafia, pẹlu ibkun nla fun Aiyeola.

No comments:
Post a Comment