Oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Party, ADC, Atiku Abubakar ti sọ pe ọdun 2027 ni yoo jẹ ọdun to gbẹyin foun lati dije fun ipo aarẹ.
Atiku to ti n dije fun ipo aarẹ lati ọdun 2007 lo sọ eyi lasiko to n dahun ibeere laipẹ yii.
Atiku sọ pe boun ko ba ti wọle sipo aarẹ Naijiria lọdun, 2027, oun yoo gba ipo naa patapata.
O ni ko si erongba lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2031 mọ.
Atiku ni igbakeji aarẹ Naijiria laaarin ọdun 1999 si 2007.
Nibi ifọrọwerọ naa ti Atiku ṣe lede Hausa lo ti ni “Rara, mo ti sọ tẹlẹ pe lẹyin eto idibo yii, nko tun ni ni dije mọ.”
O wa rọ awọn araalu lati tete lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ṣaaju eto idibo ọdun 2027.
Atiku tin gba awọn eeyan lamọran lati ma ṣe dibo nikan, bi ko ṣe pe ki wọn tun duro ti ibo wọn ni ibudo idibo lọjọ idibo.
“Lakọkọ, mo rọ gbogbo awọn to ni kaadi idibo, nitori ara wọn, mọlẹbi wọn ati ọjọ iwaju wọn, lati lọ dibo. Ọna abayọ kan ṣoṣo niyẹn si iṣoro ti wọn n koju.
“Lẹyin ti ẹ ba jade dibo tan, ki won tun ṣi duro, ki wọn ai tẹle ibo naa debi to n lọ lati rii pe wọn ka a,” Atiku sọ bẹẹ.

No comments:
Post a Comment