Akojọpọ awọn eleto aabo bii Ologun, DSS ati Amotekun ti ṣe ikọlu si buba awọn ọmọ ogun agbesunmọmi aṣekupani nipinlẹ Ondo.
Opin ọsẹ to kọja yii la gbọ ikọ awọn eleto aabo naa ṣiṣẹ wọnu igbo kijikiji ti Owo, eyi ti awọn amookunṣeka naa farapamọ si.
Nibẹ ni wọn ti pa ọkan lara awọn olori ọmọ ogun agbesunmọmi ti ISWAP, Abdussamad Ohida to n da gbogbo Naijiria laamu.
Akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ eto aabo, Zagazola Makama lo fidi iroyin yii mulẹ loju opo ‘X’ rẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni Ohida, ti wọn tun n pe ni Anwar lo n ṣe gbogbo ikọlu ipaniyan ati ijinigbe, pẹlu erongba lati gbẹsan.
O ni kaakiri ẹkun Guusu Naijiria ni awọn omo ogun ISWAP naa ti ṣagbekalẹ ibudo wọn si, lati le ṣe ikọlu nla-nla.
Bakan naa lo sọ pe olori ISWAP ti wọn pa yii, lo ti figba kan ri jẹ igbakeji olori ọmọ ogun ISWAP ni aarin gbungbun Naijiria, Abu Ikrimah, ẹni ti wọn tun n pe ni Abu Uwais.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2023 lọwọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo Naijiria tẹ Ikrimah.
Lẹyin tọwọ tẹ Ikrimah, ni Ohida dide gẹgẹ bi adari tuntun, to si n ṣiṣẹ ikọlu kaakiri ẹkun aarin gbungbun Ariwa ati Guusu orileede Naijiria, nibi to ti ṣe oniruuru eto ikọlu.
Akọṣẹmọṣẹ yii tun fidi rẹ mulẹ pe iwadii fi han pe ọrọ ti wọn fi wa Abu Uwais lẹnu wo, lo jẹ ki aṣiri bi Ohida ati ikọ yooku ṣe n ṣiṣẹ ikọlu saarin ilu.
Siwaju sii lo sọ pe Ohida n ṣe gbogbo eto lati ṣe ikọlu nla lasiko ayẹyẹ ọdun ati eto idibo ọdun 2027.
Ṣugbọn ni bayii, ọwọ palaba rẹ ti segi, ti iwadii si ti n lọ lọwọ.

No comments:
Post a Comment