Ọkọ baalu agberapa jabọ lulẹ l’Ondo, ọpọ oku lo sun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 5, 2026

Ọkọ baalu agberapa jabọ lulẹ l’Ondo, ọpọ oku lo sun


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Igbokoda nijọba ibilẹ Ilaje, ipinlẹ Ondo, nigba ti ọkọ baalu agberapa ti a mọ si ‘helicopter’ jabọ lulẹ lojiji.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aarọ oni, ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni ọkọ baalu agberapa naa jabọ lasiko to n fo lọ.

Titi di asiko ti pari akojọpọ iroyin yii ni awọn alakoso ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ ijamba naa.

Bakan naa, titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii le fidi ohun to ṣokunfa ijamba naa mulẹ.

Bẹẹ si ni ko tii sẹni to le sọ pato iye awọn eeyan to ku, tabi ti wọn farapa yannayanna.

Kete ti ọkọ baalu agberapa naa ti jabọ lulẹ, lo ti gbina.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI