Awon omo kekeeke to n jale l’Abeokuta ti foju bale ejo o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 14, 2017

Awon omo kekeeke to n jale l’Abeokuta ti foju bale ejo o

Pakopako lawon omo kekeeke tojo ori won ko ju odun merinla lo n wo niwaju adajo ile ejo Majisireeti to n gbo ejo awon omo kekeeke lojo Wesde ati Tosde ose to koja yi pelu esun merin otooto to nii se pelu fifo ile ati ole jija towo e to egberun mokandinlogun (19,000) naira.

Olori won

Ninu iwe esun ti nomba e je MA/721c/2017, eyi ti won fi kan won naa ni won ti ka awon nkan ti won ji bii pakeeti Spaghetti marun un, pakeeti lailoonu (nylon) mewaa, pakeeti oti kooki (coke) kan, ose ifoso, miliiki alagolo meta, batiri atawon nkan min in ni won so pe soobu obinrin kan ti won poruko e ni Ayoola Olajumoke ni won ti jii.

Alariya Oodua gbo pe won tare awon omo naa si ogba awon omo alaigboran titi dasiko taa sakojopo iroyin yi tan.

Nise lopo awon eeyan to wa ladugbo kan ti won n pe ni Idofin lagbegbe Elega niluu Abeokuta la enu won sile, ti won ko le pa a de lose to koja, ko da titi di bi e ti n ka iroyin yi loro awon omo kekeeke tojo ori won ko ju odun metala si merinla lo yi ti won so pe ogbologbo paraku ni won ninu ole jija si n je fun opo awon ti ri won.

Ko si nkan meji to tun je koro awon omo yi ya awon eeyan lenu bi ko se bi won tun se n soro nigba ti won n foro wa won lenu wo, ti won si rii pe ojo ti pe ti won ti wa ninu ise buruku naa.

Musa Sulaiman ti won tun n pe ni Chairman, omodun merinla ti won loun ni olori won; Abiodun Atanda; Sodiq Oloyede; Yinusa ati Tunde, ti won lomodun metala ni won lawon omo naa.

Gege b'Alariya Oodua se gbo, soobu kan ti won ti n ta orisirisi ohun jije ati mimu ni won loo ja ni nnkan bii aago mejila oru, ti won si ko opolopo oja ti won n ta nibe, ko too di pe asiri won pada tu sawon osise OPC to n so adugbo naa lowo, ti won si foju won han laaro ojo keji tasiri won tu.

Ohun ta a gbo ni pe aaye kekere kan to si sile lapa oke nibi irin ti won se yika soobu naa ni won gba wole, ati pe ka ni awon omo egbe OPC naa ko rin sasiko ni, o seese ki won ti na papa bora ko to o di pe awon eeyan mo.

Lara awon to gbe oro naa si wa leti so pe awon ko le fi oju mejeeji won sun nitori awon adigunjale to m yo awon lenu, ati pe agbalagba lawon maa n pe won lai mo pe awon omo kekeeke ni won.

Obinrin kan to.ko lati daruko e fun wa je ko ye wa pe awon omo naa maa n toro owo kaakiri, ati pe ogbon owo ti n toro ko ju pe ki won maa fimu finle lati mo awon ti won fe e ja lole.
Alariya Oodua gbo pe lesekese ni won ti fi moto ko awon omo naa lo si tesan olopaa Adatan lati loo fa won le ijoba lowo, ki won le fiya je won labe ofin.

Sulaiman ti won tun n pe ni Chairman to so pe Ajegunle nipinle Eko lawon obi oun n gbe, sugbon ile keu ni won foun si lodo Aafa Ambali to wa ladugbo Saje, ati pe iya ti Aafa naa ma fi n je oun lo je koun sa kuro nibe pelu ore oun Yinusa.

O so pe ko too di pe awon loo ja soobu naa, Abiodun lo pe akiyesi awon sii wi pe ko ko oja won wole, yoo si je anfaani fawon lati ji eru ko nibe, eyi lo fa a tawon fi pada lo sibe ni nnkan bi aago mejila oru tawon eeyan ti loo sun.

Yinusa nigba toun n soro so pe oun ko niya mo, Ilugun ni baba oun gbe ati pe odo Aafa ile keu loun n gbe ni Saje, sugbon nina to maa n na awon lo je koun ati Sulaiman sa kuro nibe.

Tunde ni ti e lakoko toun naa n soro so pe, Eko ni baba oun gbe, Soyoye ni mama oun n gbe ati pe Ilugun lodo mama to bi baba oun loun gbe. O so pe ileewe Oke Isagun loun n lo lagbegbe Kola Odunsi niluu Eko loun n lo.

Sodiq nigba toun naa n soro so pe Itoku lodo mama to bi baba oun loun gbe nitori pe mama oun ti ku.

Abiodun to so pe adugbo kan ni Ajitadun loun n gbe lodo mama oun ti won n pe ni Yeye nitori Yemoja to n bo ni won se n pe loruko naa. O ni Sango ni baba oun n gbe.

Lati fidi isele naa mule, agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n b'Alariya Oodua soro lori isele, o so pe looto ni, ati pe lesekese ti won ti ko won de tesan adatan ni Komisana won, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki won maa ko won bo ni Eleweran.

Oyeyemi so pe omo kekeeke ni won, awon ko gbodo foro won fale lo je kawon gbe won lo si kootu to n sedajo awon kekeeke, iyen Juvenile Court, sugbon toun ko tii le so pato ibi ti won ba ejo naa de.

O loun mo daju pe ile awon omo alaigbonran ni won ma a gbeyin si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI