Eyi ni bi won se yan Iyaloja Oja-Odan tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 15, 2017

Eyi ni bi won se yan Iyaloja Oja-Odan tuntun

Idunnu subu lu ayo awon ara Oja-Odan to wa nijoba ibile Yewa North lose to koja nigba ti Oba Gbadewole Kehinde Olugbenle, Olu Ilaro ati Oba alaye tile Yewa lapapo fowo si Oloye Arabinrin Birikisu Adebayo gege bi Iyaloja Oja-Odan ti yoo maa sakoso oja naa.

Oba Olugbenle
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni leyin ti awon oloye ti ko din ni mejilelogota (62) ti so pe oun lawon fe gege bi Iyaloja Oja-Odan naa, ni won mu Arabinrin Birikisu to tun je Alaaja lo siwaju Kabiyesi, Oba Olugbenle pe ko bawon fowo sii.

AWIKONKO gbo pe Alaaja Birikisu Adebayo lo ti je gege bii asoju Iyaloja Oja-Odan to wa nijoba ibile idagbasoke Ketu latigba ti eni to je Iyaloja to wa nibe ti papoda, to ti dagbere faye lodun die seyin.

Nigba to n soro lakoko to n bawon eeyan soro lori Alaaja Birikisu, Olu Ilaro so pe leyin opolopo ise iwadi ati ibeere lowo awon ara oja pelu awon ara Oja-Odan ati agbegbe e wi pe se won fowo si obinrin naa, ti gbogbo won si so pe oun gan an lawon fe ko gba ise naa nitori pe o kaju osuwon.

O so pe iwa olori e latigba ti won ti yan an gege bi asoju Iyaloja ko se e fenuso nitori tawon eeyan n gba ti e, to si tun n sagbateru ife, alaafia ati isokan wo inu ilu.

Nigba tawon naa n soro, Babalaje ile Yewa, Oloye Adewale Adesina Saranda ati Alaaja Yemisi Abass toun je Iyaloja gbogbo Yewa dupe gidigidi lowo gbogbo awon Oba ile Yewa lapapo fun atileyin won pelu bi won se yan Iyaloja Oja-Odan naa pelu ileri ifowosowopo.

Oja igbalode
Oloye Saranda ninu itan ijoba ibile Yewa North nipa eto oro aje ati bi owo se n wole, Oja-Odan ati Ijoun ni won ni akosile to ga ju nipa ibi towo ti n wole nipinle Ogun.

Nigba ti n gba Iyaloja tuntun naa lamoran, O so pe ko tubo rii daju pe isokan, ife ati alaafia tubo n joba sii ninu oja naa, ati pe ki won rii pe won pana gbeborun ati sisoro eni leyin, nitori pe ko si nkan to n da ilu ru, bi ko se awon iwa naa.

Lara awon to tun wa nibi eto yiyan Iyaloja tuntun naa ni Arabinrin Alice Modupe Adekunle, Ogbeni Saka Salau to je akowe egbe oloja ni Oja-Odan atawon agbaagba ninu oja naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI