O Tan O: Atiku loun ko le kuro ninu ẹgbẹ PDP mọ laelae - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 31, 2018

O Tan O: Atiku loun ko le kuro ninu ẹgbẹ PDP mọ laelae

Oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, to tun ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ orileede yii, Atiku Abubakar, ti sọ lọjọbo, Tọsidee, ana an pe oun ko le fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ koda bi wọn ko ba foun ni  tikẹẹti lati jade dupo.

Iluu Minna ni ọkunrin naa ti sọrọ yii lakooko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọrọ ni ọfiisi nla ẹgbẹ naa. O sọ pe oun nigbagbọ pe oun ni wọn yoo fun ni tikẹẹti lati dije iyẹn ti wọn ba ṣe ohun gbogbo, bo ti tọ ati bo ti yẹ.


Bakan naa lọkunrin yii tun ṣabẹwo de ọdọ awọn aarẹ oloogun meji ninu irinajo naa, awọn naa ni Ọgagun Ibrahim Babangida ati  ati Ọgagun Abdusalam Abubakar.

O rọ awọn aṣaaju ẹgbẹ naa lati ri i pe wọn fọgbọn ṣe ohun gbogbo lati le jẹ ki ibo abẹle ninu ẹgbẹ naa lọọ ni irọwọrọsẹ.O ni oun ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu gbogbo wọn fun ibo abẹle naa.


O sọ pẹlu idaniloju pe yala wọn foun ni tikẹẹti tabi wọn ko foun oun yoo sa ipa oun fun ilọsiwaju ẹgbẹ naa.O ni gbogbo awọn tawọn fẹẹ dije fun pamari lawọn ti jọ fẹnu ko lati jọ ṣiṣẹpọ fẹni to ba yege ki wọn si wa ni isọkan.O loun wa si ipinlẹ Niger lati jẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ ṣatilẹyin foun fun ibo abẹle naa.

Lara awọn to tẹle nii Ọtunba Gbenga Daniel to jẹ alakoso agba ipolongo fun Abubakar Atiku atawọn mi- in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI