Onarebu Jumokẹ Ọkọya-Thomas ni ki APC mu Kẹmi Nelson so - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 31, 2018

Onarebu Jumokẹ Ọkọya-Thomas ni ki APC mu Kẹmi Nelson so

Aṣaaju awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Ọnarebu Jumokẹ Ọkọya-Thomas, ti sọ fun awọn agba ẹgbẹ naa pe ki wọn kilọ fun Oloye Kẹmi Nelson, to jẹ olori awọn obinrin fẹgbẹ oṣelu ọhun nilẹ Yoruba, lati so ewe agbejẹ mọwọ ati pe bi aja ba n sin win, ko mọ ile olowo ẹ, ki wọn tete muu so.


O ni ki wọn kilọ fobinrin naa ko dẹkun lati maa kan oun labuku tabi yẹyẹ oun nita gbangba, nitoro ki i ṣe pe oun naa ko mọ nnkan to yẹ koun ṣe.

O sọrọ yii ninu atẹjade to fi ranṣẹ sawọn oniroyin. O ni gbogbo abuku tobinrin naa fi n kan oun latigba toun ti depo aṣaaju awọn obinrin fẹgbẹ oṣelu APC lati inu oṣu karun un, ti to gẹ.

Atẹjade naa lọọ bayii pe ‘Eyi ni lati jẹ kawọn araalu mọ nipa iwa ainitiju ti Oloye Kẹmi Nelson hu, to n ko abuku ati ẹrẹ ba Ọnarebu Jumọkẹ Ọkọya-Thomas. Lọjọ Aje, Monde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ni Kẹmi Nelson atawọn tọọgi mẹfa ja wọ ọfiisi alaga wa iyẹn, Ọnarebu Tunde Balogun nigba ta a wa ninu ipade oloye ẹgbẹ’

O sọ pe ọkan lara awọn obinrin tọọgi naa, Ayọ Alli Balogun sọ foun loju awọn oloye ẹgbẹ yooku pe oun yoo foju oun ri mabo.

Kaka koun fun un lesi, ṣe loun jade ninu ọfiisi alaga naa, ṣugbọn siyalẹnu, oun, ṣe ni Ayọ tọọgi  naa lọọ ba amugbalẹgbẹ oun, Alaaja Abiọdun,to si i doju ija kọ ọ debi pe wọn sare gbe obinrin naa lọọ si ọsibitu nibi to ti gba itọju.

Jumọke Ọkọya- Thomas tun sọ ninu atẹjade naa pe gbogbo ọna loun gba lati fi nawọ ifẹ si Kẹmi Nelson ṣugbọn ti gbogbo rẹ ja si pabo.

O wa parọwa fawọn agba ẹgbẹ naa pe ki wọn pe Kemi Nelson nibi ti wọn ti le ba a sọrọ, ki wọn si kilọ fun un pe ko jawọ ninu gbogbo iwa radarada ti obinrin naa hu ti ko yẹ ki won maa ba a nibẹ pẹlu ipo to wa, nitori o ti fẹẹ maa ga ju ẹmi oun lọ bayii, to si fẹẹ maa ṣakoba fawọn iṣẹ to wa niwaju oun.

O ni gbogbo ọna loun fi n yẹba fun obinrin ọhun nitori wahala ẹ yii, ẹni toun gbe sibi giga tẹlẹ. O ni nnkan ti ẹgbẹ  oṣelu APC nilo lakooko yii ni isọkan lati le fi koju ibo to n bọ lọna. Bakan naa lo gba awọn alatilẹyin ẹ niyanju lati gba alaafia laaye laarin ara won ki wọn si jọ maa wa bi ẹgbẹ naa yoo ṣe bori ninu ibo to n bọ lọna naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI