Agbarijọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede yi ti fariga pe awọn ko ṣetan lati gba ẹgbẹrun
mẹtadinlọgbọn (27,000) naira owo oṣu tuntun tijọba apapọ sọ pe awọn yoo maa san
fawọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi owo oṣu tuntun.
Onii Tuside la gbọ pe wahala bẹ silẹ laarin awọn agbaagba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ
atawọn tijọba yan lati dari ipade naa. Akọwe agba, Dokita Peter Ozo-Eson lo fi ọrọ
yi naa sita lẹyin ipade ti wọn ṣe, eyi to fori sanpọn.
Okunrin naa fi ẹdun ọkan ẹ han sita,o sọ pe o ṣeni laanu pe igbimọ tijọba
apapọ gbe kale lati ri si ọrọ owo oṣu naa ko ṣe nnkan tawọn oṣiṣẹ n fẹ, wọn ko
sọrọ sibi ti ọrọ wa, ọtọ ni nnkan ti wọn sọ lẹnu.
O ni ko yẹ kijọba maa da nnkan ti ko pẹ duro, ki wọn si maa sun ọrọ owo oṣu
ti ko gba wahala siwaju, ko si tun wa a jẹ pe owo ti ko to nnkan ni wọn ma a gbe
wa siwaju awọn lati gba a.
Ozo-Eson wa a sọ pe awọn ti sun ipade miran si ọjọ Fraide to n bọ yii lati mọ ibi tawọn yoo fori o\rọ naa ti si.
No comments:
Post a Comment