ILE ẸJỌ JU ỌPẸYẸMI SẸWỌN LORI ẸSUN PATA TO JI KA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 22, 2019

ILE ẸJỌ JU ỌPẸYẸMI SẸWỌN LORI ẸSUN PATA TO JI KA


Titilayọ Agbaje

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọdọmọkunrin kan, Ọpẹyẹmi Adeleke lori ẹsun ti wọn fi kan an pe pata oni pata lo n ji ka kaakiri ilu Oṣogbo, paapaa bo tun ṣe lọọ ji pata gendebinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Gift ka.

Aago kan oru ọjọ Monde, ọjọ kokanlelogun oṣu kinni ọdun yii lọwọ tẹ Ọpẹyẹmi, ọmọ ọdun metalelogun naa.

Agbegbe Agọwande niluu Oṣogbo ni Ọpẹyẹmi ti ji awọtẹlẹ naa ka.

Adajọ ile ẹjọ Majisireeti kan l'Oṣogbo, Mary Awodele si ti paṣe bayii pe ki wọn ju Ọpẹyẹmi s’ẹwọn titi di oṣu to n bọ tidajọ yoo tun waye lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI