Ṣé l'ọrọ di boolọ ó yàgò lọ́nà lónìí nígbà tí awuyewuye kan jáde síta wí pé àwọn akọroyin mẹ́wàá tí wọn ń ṣiṣẹ pẹlu Gómìnà ipinlẹ Akwa Ibom, Emmanuel Udom tí kò àrùn aṣekupani, ìyẹn Koronafairọọsi.
Lára àwọn akọroyin náà tí wọn sọ pé ayẹwo fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé wọn tí kò àrùn Koronafairọọsi ni ayaworan, akọroyin, aṣojukọroyin àtàwọn òṣìṣẹ́-kọroyin to jẹ tijọba, ìyẹn information officers.
Ọjọ́ Iṣẹgun, Tuside to kọjá yìí là gbọ pé ọkàn lára àwọn akọroyin náà ṣàkíyèsí wí pé ara òun kò yà, tí wọn sì ṣàyẹ̀wò COVID-19 fún un, tó sì jẹ pe wọn fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé àrùn náà wá lára rẹ.
Èyí ló mú kí ẹrú bá àwọn akọroyin yòókù tí wọn jọ farakinra táwọn náà sì lọ ṣàyẹ̀wò laarọ Ọjọru, Wẹside, táwọn mẹsan lára wọn sì ti kó àrùn yìí.
Ṣáájú àsìkò yìí ni akọroyin orí ayélujára kan tí gbé ìròyìn kan síta wí pé lára àwọn kọmiṣanna nipinlẹ náà tí ni àrùn yìí, ṣùgbọ́n tijọba sọ pé ìròyìn ẹlẹjẹ lásán ni.
Ohun táwọn èèyàn ń sọ ní pe o ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara àwọn kọmiṣanna yìí làwọn oniroyin náà tí kò àrùn yìí, nítorí pé oorekoore ni wọn ń wá ní ọfiisi Gómìnà fún ìpàdé àwọn oniroyin, ìyẹn Press Conference.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, oludamọran pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn àti akọwe Gómìnà, Ọgbẹni Ekerete Udoh sọ pé ìròyìn náà kò lẹsẹ nilẹ rárá nítorí pé ayédèrú ni.
Ekerete sọ pé ìròyìn agbelẹrọ pátápátá gbaa ni.
No comments:
Post a Comment