RAMADAANI! ỌGA VGN N'IPINLẸ OGUN KÍ ÀWỌN MÙSÙLÙMÍ, Ó TÚN ṢÈLÉRÍ ÀÀBÒ TO PÉYE FÁWỌN ARÁÀLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 24, 2020

RAMADAANI! ỌGA VGN N'IPINLẸ OGUN KÍ ÀWỌN MÙSÙLÙMÍ, Ó TÚN ṢÈLÉRÍ ÀÀBÒ TO PÉYE FÁWỌN ARÁÀLÚ


Bí gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí jákèjádò àgbáyé ṣe ń ṣayẹyẹ Ìtunu aawẹ Ramadaani Ọlọdọọdun lónìí, Kọmanda àwọn ẹṣọ ààbò fijilante, ìyẹn VGN nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ọlanrewaju Nureni Adedoyin tí kì wọn kú ajọyọ.

Kọmanda Ọlanrewaju Adedoyin nínú atẹjade tó fi síta laarọ òní ọjọ́ Àìkú, tíì ṣe Sande, èyí tó fi kí àwọn Mùsùlùmí lo tí sọ pé káwọn èèyàn náà fọkàn wọn balẹ̀ nítorí pé kò sí ìbẹ̀rù fẹnikẹni.

Ọkùnrin tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa iṣẹ eto ààbò làwọn ilé ẹ̀kọ́ loriṣiriṣi náà tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun lórí ipa tó ń kó láwùjọ àwọn eleto ààbò.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Inú mi dùn lónìí láti bá gbogbo àwọn èèyàn wa ninu ẹsin Isilaamu ṣe ajọyọ ayẹyẹ Ìtunu aawẹ Ramadaani to ń lọ lọ́wọ́ yìí. Mí ó lè ṣai dúpẹ́ fún ifọwọsowọpọ aráàlú lórí bí wọn ṣe ń tẹle òfin àti ìlànà Konilegbele lásìkò tí ajakalẹ àrùn COVID-19 ń dá àgbáyé, pàápàá Nàìjíríà láàmú, èyí ti ipinlẹ náà kò gbẹyin.

"Gẹ́gẹ́ bí ileeṣẹ tó ń ṣe iranlọwọ fáwọn aráàlú àti ìjọba láti ríi pé ìwà burúkú àti ọ̀daràn d'ohun ìgbàgbé, a ń fi àsìkò yìí fi ọkàn gbogbo èèyàn balẹ̀ nítorí pé kò sí ìbẹ̀rù fẹnikẹni. 

"Mo fẹ́ kí ẹ mọ pe gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wá ní wọn tí wá làwọn agbègbè káàkiri láti jẹ ki òfin ìjọba lórí konilegbele fi ẹsẹ múlẹ̀, èyí tí kò sì nii faaye gba ìwà ọ̀daràn làwọn àwùjọ wá." 

Bákan náà lo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Dapọ Abiọdun fún akitiyan rẹ láti fọwọsowọpọ pelu ileeṣẹ VGN, pàápàá nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI