Ọlaide Ọṣinuga, Eko
'Aye mi temi bami' lọrọ ibanujẹ ti wọn lo o kọkọ jade lẹnu baale ile ẹni ọdun mẹtadinlaadọta kan, Chinebere Innocent kan ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji mi in to n ṣe to kọja ko maa ja mọto onimọto gba lọ kaakiri igboro ilu Eko.
Bi Innocent ba ti ja mọto naa gba tan, ipinlẹ Abia lo maa n gbe e lọ lati lọ ta a danu ki aṣiri ma ba a tu.
Ọjọ kẹta oṣu yii, iyẹn Ọjọbọ-Tọsidee to kọja yii lọwọ palaba Innocent, ọmọ bibi ilu Abia naa segi lagbegbe Ọjọta nilu Eko pẹlu mọto jiipu SUV Prado pẹlu nọmba idanimọ MUS 136 ET to ja gba lọwọ ẹni to ni i.
Awọn ọlọpaa Rapid Response Squad (RRS) nipinlẹ Eko ni aṣiri rẹ tu si lọwọ, ti wọn si rọwọ to o.
Ọwọ oṣiṣẹ eleto aabo kan to n wa a la gbọ pe Innocent ti digun gba mọto naa lasiko tiyẹn fẹẹ paaki rẹ sinu ọgba ile to gbe e lọ.
Nigba to n sọrọ lasiko tọwọ tẹẹ, o sọ pe "Bi mo ṣe n bọ lati ọdọ ẹgbọn mi obinrin to le mi danu, ti ko jẹ ki n wọle ni mo ṣakiyesi mọto naa to n ṣiṣẹ lọwọ, ṣugbọn ko seeyan ninu ẹ. Agbegbe Gbagada ni. Bi mo ṣe wọnu ẹ ni mo ti n wa a lọ si ipinlẹ Abia, oju ọna Eko si Ibadan ni mo wa ko to di pe ọwọ tẹ mi lagbegbe Ọjọta."
AWIKONKO gbọ pe ẹni kan to n ṣe Olumide Oluwayọmi to n gbe lagbegbe Gbagada lo ni mọto naa, ẹni ti wọn sọ pe iṣẹ wọnlẹ-wọnlẹ lo n ṣ.
No comments:
Post a Comment