Ọrọ buruku toun tẹrin: Igboho fo fẹnsi wọ Aafin Kabiyesi l'Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 6, 2021

Ọrọ buruku toun tẹrin: Igboho fo fẹnsi wọ Aafin Kabiyesi l'Ekiti


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Ọrọ buruku toun tẹrin nla gba a lọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ, olori awọn ajijagbara ilẹ Yoruba jẹ lọjọ Satide ana nigba ti wọn loo fo fẹnsi wọnu ọgba aafin Ewi tilu Ado Ekiti, Ọba Rufus Adeyẹmọ Aladesanmi kẹta.
 
Ohun ta a gbọ ni pe ipolongo ifẹhonu han alalaafia lati da orilẹede Yoruba, iyẹn Oduduwa Nation silẹ ni Oloye Adeyẹmọ tọpọ tun mọ si Sunday Igboho gbe lọ silu Ado Ekiti lọjọ naa.
 
Lati nnkan bi aago mẹjọ aarọ lawọn alatilẹyin Igboho ti n duro dee ni garaaji atijọ to wa nilu Ado Ekiti ko to di pe wọn pada lọ si garaaji Fajuyi nibi ti wọn ti lọọ pade Igboho funra rẹ.
 
A gbọ pe bi Igboho ṣe de ni nnkan bi aago marun-un kọja iṣẹju meji to lo ti n bẹ gbogbo wi pe ki wọn ba binu wi pe oun pẹẹ de, ati pe awọn eto kan loun n to lọwọ, to fa a toun ko fi tete de.

Wọn ni bo ṣe debẹ lo wo o pe koun kọkọ ṣe abẹwo si ori ade lati gba adura lẹnu Kabiyesi lori eto ti wọn wa a ṣe naa. Bi wọn ṣe n lọ la gbọ pe Kabiyesi, Ọba Aladesanmi ti paṣẹ pe kawọn ẹṣọ ẹnu ọna rẹ tilẹkun pa, ki wọn si ma jẹ kẹnikẹni wọle sinu ọgba oun tori pe oun ko fẹ alejo.
 
Gbogbo igbiyanju Sunday Igboho ati awọn alatilẹyin rẹ to ko dani lati wọnu Aafin naa ri Kabiyesi lo ja si pabo, nigba ti wọn ni Igboho ri i pe Kabiyesi ko fẹẹ ri oun lo ba ni kawọn eeyan gbe oun gba ori fẹnsi lati wọle sinu ọgba naa.
 
Bo ṣe wọle lo tun ri i pe ko saaye foun lati ri Ọba Aladesanmi toun fẹẹ gba adura lẹnu ẹ, eyi gan an lo fa a to fi binu binu jade, to si ba tirẹ lọ.
 
Nigba to n bawọn eeyan sọrọ lọjọ naa, Igboho sọ pe ko sẹni to le da awọn duro lati ja fun idasilẹ ati ominira ilẹ Yoruba, to si tun ni ko si eto idibo ti yoo waye lọdun 2023 nilẹ Yoruba, ayafi bawọn alaṣẹ ba bu ọwọ lu idasilẹ Yoruba.
 

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI