Kwara: Eyi ni bawọn to ku diẹ kaato fun naa ṣe fẹẹ jẹ anfaani eto ilera ọfẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 1, 2021

Kwara: Eyi ni bawọn to ku diẹ kaato fun naa ṣe fẹẹ jẹ anfaani eto ilera ọfẹ


Lonii, Ọjọbọ, Tọside ni ijọba ipinlẹ Kwara tun gbe ikede ati ipolongo ọna lati jẹ anfaani eto ilera ọfẹ, iyẹn fun gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ naa, to fi mọ awọn to ku diẹ kaato fun kaakiri ipinlẹ naa de awọn agbegbe kọọkan.
 
Ẹlẹẹkeje iru ẹ ni wọn pe anfaani yii, ta a si gbọ pe fun anfaani lati jẹ ki gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa wa ni ilera pipe ni eto yii wa fun.
 
Ọsibitu Igbo-Ọrọ to wa niluu Ọffa ni gomina AbdulRazaq ti sọ pe ki awọn eeyan le wa ni ilera ati alaafia pipe lo jẹ kawọn maa gbe gbogbo igbesẹ yii, ati pe ilera ati igbayegbadun awọn araalu lo jẹ oun logun.
 
O ni ki i ṣe boun ṣe n mu awọn ileri oun ṣe lo maa n jẹ idunnu foun, bi ko ṣe lati maa ri ẹrin ati idunnu loju awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI