AbdulRazaq sọ Sawyerr di agbenusọ ipinlẹ naa lagbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 1, 2021

AbdulRazaq sọ Sawyerr di agbenusọ ipinlẹ naa lagbaye


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti kede Ọmọwe Lọla Sawyerr gẹgẹ bi agbẹnusọ rẹ nilẹ Amẹrika atawọn orileede mi in kaakiri agbaye.
 
Ana ti i ṣe ọgbọn ọjọ, oṣu kẹfa to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq kede Sawyerr, ọmọ ipinlẹ naa to fi ilu Georgia ṣe ibugbe gẹgẹ bi agbẹnusọ rẹ.
 
Gbogbo awọn nnkan to ni i ṣe pẹlu ọrọ ilẹ okeere nipa Gomina AbdulRazaq la gbọ pe Ọmọwe Sawyerr yoo maa gbẹnusọ fun.
 
Ọmọwe Sawyerr, gẹgẹ ba a ṣe gbọ kawẹ gboye ni fasiti Clark Atlanta ati fasiti Walden, bẹẹ lo tun ti ṣiṣẹ kaakiri ilẹ Amẹrika bi i olukọ, agbowo ori, oluṣiro, ati bẹẹ lọ.
 
Obinrin naa ti figba kan ri jẹ igbakeji alakoso banki Equity lorileede Naijiria, to si tun jẹ Ọmọwe eto ẹkọ ninu ila eto ẹkọ ilẹ Georgia.
 
Wọn ni ki i ṣe pe wọn deede yan Sawyerr, bi ko ṣe lati le mu ki awọn ọmọ ipinlẹ naa ti wọn wa loke okun jẹ anfaani eto ijọba awaarawa, ati lati mọ bi nnkan ṣe n lọ ninu ijọba lo jẹ ki wọn yan an.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI