Nkan de! Asọtẹlẹ Wolii Ayodele lori ọrọ Ẹbola ti wa si imuṣẹ o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 16, 2021

Nkan de! Asọtẹlẹ Wolii Ayodele lori ọrọ Ẹbola ti wa si imuṣẹ o


Lakooko ta a pari akojọpọ iroyin yii, inu ibẹrubojo lawọn eeyan ilẹ adulawọ, iyẹn Afrika wa lori bi asọtẹlẹ gbajugbaja Wolii Elijah Ayọdele, alaṣẹ ati oludari ṣọọṣi, INRI Evangelical Spiritual Church lori ọrọ ajakalẹ arun Ẹbola.

Ninu oṣu kẹfa, ọdun yii ni Wolii Ayọdele gbe iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun rẹ, to pe ni Warnings to the Nation jade, nibi to ti mẹnuba oriṣiriṣi awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lagbaye.

Lara rẹ lo ti sọ pe ajakalẹ arun Ẹbola yoo tun bu yọ lawọn agbegbe kan nilẹ Afrika, eyi ti yoo mu ibẹrunbojo bawọn eeyan, paapaa awọn ti wọn ba kofiri rẹ lọdọ.

Wolii Ayọdele sọ pe o yẹ kawọn eeyan tete bẹrẹ si i gbadura lodi si arun yii, ko ma ba a ṣeku pa awọn eeyan lai lero.

Abala ọọdunrun-le-ni-mẹtadinlọgbọn (327) ni Wolii Ayọdele ti mẹnuba asọtẹlẹ naa, to si sọ pe yoo waye lọdun yii.

 Ni nnkan bi ọjọ meji si mẹta sẹyin ni iroyin jade nilẹ Ivory Coast sọ pe awọn ti ni akọsilẹ arun Ẹbola fun igba akọkọ lẹyin ọdun marundinlọgbọn ti arun naa ti wa nita.

Ẹri maa jẹ mi niṣo, asọtẹlẹ naa ree:

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI