Pasitọ to yi orukọ ṣọọṣi MFM pada lọna eru lati lu jibiti padanu nile-ẹjọ kotẹmilọrun l'Amẹrika - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 16, 2021

Pasitọ to yi orukọ ṣọọṣi MFM pada lọna eru lati lu jibiti padanu nile-ẹjọ kotẹmilọrun l'Amẹrika


Ile-ẹjọ ilẹ Amẹrika kan ti paṣẹ wi pe ki wọn da ṣọọṣi Ori Oke Ina ati Iṣẹ Iyanu, Mountain of Fire and Miracles Ministries, ẹka ti BOWIE, nilu Maryland pada fun awọn to ni i lai fi akooko ṣofo.
 
AWIKONKO gbọ pe Pasitọ Lawrence Adetunji ti wọn fi ṣe alakoso ṣọọṣi MFM ni ẹka ti BOWIE yii lo gbimọ papọ pẹlu awọn mókanla miran lati yi orukọ ṣọọṣi naa pada, ti wọn si sọ ọ di ti wọn.
 
Orukọ ta a gbọ pe wọn yi MFM pada si ni Christ The Truth Ministries, eyi ti wọn ni ko tẹ awọn adari ṣọọṣi yii lapapọ lọrun, ti wọn fi gba ile-ẹjọ lọ, ti ile-ẹjọ si da wọn lare.
 
Inu oṣu kẹsan-an, ọdun 2017 la gbọ pe ṣọọṣi MFM lapapọ, eyi to wa l'Ekoo ati Nevada gba ile-ẹjọ Circuit Court for Prince George’s County to wa nilu Maryland, USA lọ, pẹlu ipẹjọ ti nọmba rẹ jẹ CAL616-26532.
 
Nibẹ ni wọn ti n bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ da Pastọ Adetunji, iyawo ẹ, ati awọn mọkanla miran lọwọ kọ lati yi orukọ ṣọọṣi naa kruo lorukọ wọn, ti ile-ẹjọ si gba bẹẹ fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI