Ó mà ṣe o! Man U gbàlejò ọ̀ràn ní Old Trafford, Liverpool ṣe wọ́n ṣákaṣàka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 25, 2021

Ó mà ṣe o! Man U gbàlejò ọ̀ràn ní Old Trafford, Liverpool ṣe wọ́n ṣákaṣàka


Gbogbo awọn ọmọ ati ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ni wọn ko le gbagbe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 pẹlu bi akẹgbẹ wọn, Liverpool ṣe wa gbo omi ewuro si wọn loju, nibi ifigagbaga to waye nibẹ.
 
Aami ayo marun-un si oodo ni Liverpool fi yẹyẹ wọn, to si mu ki gbogbo awọn ololufẹ Man U kawọ mọri pe alejo ọran lawọn gba lotitọ.
 
Naby Keita lo kọkọ gba aami ayo akọkọ wọle ni iṣẹju marun-un ti wọn bẹrẹ ifigagbaga naa, ko to di pe Diago Jota fi ọba lee ni iṣẹju mẹtala.
 
Itan tuntun ni idije naa fi balẹ fun gbajugbaja agbaọọlu ọmọ orilẹ-ede Egypt nni, Mohamed Salah pẹlu bo ṣe gba aami ayo mẹta wọle ninu ifigagbaga naa ni iṣẹ mejidinlogoji, iṣẹju marundinlaadọta le marun {45:5m} ati aadọta iṣẹju.
 
A gbọ pe ṣe ni Cristiano Ronaldo ti awọn ọmọ Man U gbojule gbiyanju agbara rẹ lati gba aami ayo wọle, ṣugbọn ti awọn to di ẹyin mu sọ pe ko saaye fun un.
 
Idije naa jẹ ko ye wa ẹyin awọn Man U ṣi silẹ gidigidi, eyi to faaye silẹ fun awọn Liverpool lati dana iya bọlẹ fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI