Ìdìbò Gbogboogbò ẹgbẹ́ APC l'Ékòó: A ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wa padà nílé-ẹjọ́ - Fouad Oki ṣèlérí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 24, 2021

Ìdìbò Gbogboogbò ẹgbẹ́ APC l'Ékòó: A ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wa padà nílé-ẹjọ́ - Fouad Oki ṣèlérí


Fouad Oki, ọkan lara awọn oludije alaga fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, ti sọ pe pẹlu gbogbo nnkan ti wọn foju oun atawọn eeyan oun ri ti wọn ko jẹ kawọn raye wọle lati ṣojuṣe wọn gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ awọn ṣetan lati gba ile-ẹjọ, lẹyin tawọn ba gbe gbogbo igbesẹ to yẹ kawọn gbe.

O sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ, o sọ pe idajọ kan ti wa nilẹ,tawọn gba a nile- ẹjọ, eyi ni ko si fi anfaani silẹ fawọn lati lọ ṣe ti wọn lọtọ. O sọ pe gẹgẹ bi aṣẹ tile-ẹjọ ọhun pa, awọn oludije kan ko yẹ ki wọn ni anfaani lati wa nibi ti wọn ti dibo lọjọ naa, amọ ti awọn kan to pe ni atunnida, ti wọn fẹẹ tun ile aye rọ, to ni wọn sọ pe a fori o fọrun, bawọn yoo ṣe ṣe niyẹn.

Ọkunrun naa sọ pe ‘’Bi a ba wa lọ ṣeto tiwa ni ibo mii in, ti a ko jọ mu oju aje ko onisọ, awọn oludibo ti ko yẹ ko dibo, a ko nii le ṣe itọkasi fun wọn. Nitori nnkan ti wọn ṣe, o ma la ẹwọn fun awọn ti wọn kọ eti ikun si ohun ti ile- ẹjọ sọ.

Fouad tun ṣalaye pe pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe n lọọ yii, awọn yoo si pada lọ sile-ẹjọ, lẹyin igba ti ikọ to wadii ehonu ba de, ti wọn ba pari iṣẹ wọn, awọn yoo pada lọ sọ fun wọn pe ṣe lawọn kan kọ eti ikun si aṣẹ ile ẹjọ.

 O tun sọ pe "Ibo ta a di nijọba ibilẹ ati ti wọọdu, a di ti wa lọtọ, awọn naa ṣe ti wọn lọtọ, nitori pe a ko tii gba idajọ nile ẹjọ, lẹyin eto idibo ijọba ibilẹ, nile ẹjọ fun wa idajọ pe awọn ijọba ibilẹ ati awọn alakoso adugbo, ti wọn ko ṣe ni ilana ohun ti ofin ijọba apapọ sọ, lori pinpin awọn ijọba ibilẹ si yẹlẹyẹlẹ, ti ko si tii bofinmu, wọn ko gbọdọ jẹ awọn ti wọn yoo wa ninu oludibo, idi niyẹn ta a ṣe ko tọ wọn lọ, bo tilẹ jẹ pe agabagebe lati da nnkan ru, ki wọn maa tẹle ofin, ki wọn kọ eti ikun si ile-ẹjọ gbe silẹ, wa ninu wọn, awa ko ro iyẹn rara."

Igbakeji alaga fẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ nipinlẹ Eko naa tun sọ pe awọn fẹẹ fi han gbogbo aye awọn eeyan naa ko ni ibẹru Ọlọrun ati ofin ilẹ wa, idi niyẹn tawọn fi darapọ mọ wọn. O waa sọ pe awọn ti wọn lọ ṣe ibo ti wọn nibo mii in, awọn ni lati gbe oṣuba fun wọn, nitori wọn ko fẹẹ jẹ ko di jagidijagan to le mu ẹmi eeyan lọ.

Lori ibi ti nnkan de bayii, ọkunrin naa sọ pe ''Gẹgẹ bi ilana ofin ẹgbẹ wa, ti wọn fi le lẹ, ti eto idije ba ti wa, wọn maa n fi anfaani silẹ fun gbigbọ ehonu, awọn ti wọn ba rii pe eto yẹn ko ja geere, a ti fi iwe ranṣẹ si oluulesẹ ẹgbẹ wa ni orileede ni Abuja, a n reti ikọ, awọn ti wọn yoo wa gbọ ehonu lẹnu wa lati le ri aridaju bo ṣe jẹ.''

''Lẹyin naa ni a o tun maa reti esi igbimọ naa, gẹgẹ ilana ofin atawọn agbekalẹ to yẹ, lẹyin naa la o wa mọ ibi to ku ta a fẹ rin si. Amọ a ni aridaju pe pẹlu ogo ti Ọlọrun, awọn to n bọ, awọn ti wọn ko ni fi ọkan bọkan ni wọn yoo jẹ''.

"Ohun ni mo ṣe sọ fawọn eeyan wa, awọn oludibo ti wọn ko fun ni anfaani ni pe ki wọn fi ọkan balẹ, adun ni yoo gbẹyin ewuro''.

Bẹẹ lo tun ṣalaye nnkan ti oju wọn ri lọjọ ti wọn dibo, o ni ''Gẹgẹ bi eto ati ilana idije awọn alakoso ẹgbẹ nipinlẹ ti ipinlẹ, awọn alakoso wa ni apapọ lo ni eto yẹn,awọn ni yoo si fawọn to maa ṣe akoso ranṣe sawọn ijọba ipinlẹ.o ṣe ni laanu pe awọn to wa si Eko, ti Oloye Adebayọ Adelabu Pẹnkẹlẹmẹsi jẹ adari wọn, o jẹ ibanujẹ ọkan pe wọn gbabọde fẹgbẹ lati ara ihuwasi, pẹlu iseesi wọn.

O ni eyi to daa lori pe nigba ti wọn ran ikọ yẹn waa si Eko, Lọjọruu, ni wọn ti de ti wọn ko fi ara wọn fawọn ọmọ ẹgbẹ tabi oludije pe awọn ti de si ipinlẹ naa, awọn ko ri wọn rara titi di ọjọ Jimọh, ti Gomina Ipinlẹ Eko fi pe oun pe Ọgbẹni Fouad, a ku akitiyan ati igbiyanju, bawo ni ọla yoo ṣe ri, mo wa ni ọla bawo?

Fouad tun sọ pe ''Mo wa a sọ fun wọn pe a ko ri awọn ikọ ti wọn ran wa, wọn ko ṣe ijokoo kankan ki wọn fawọn oludije ni anfaani, ati pe paapaa julọ mo ti fiwe ranṣẹ si oluuleṣẹ wa l’Abuja, lati bi ọsẹ kan pe gẹgẹ bi ilana, gẹgẹ bi ofin, ki wọn fun wa niwee ti orukọ gbogbo awọn oludije, gẹgẹ bi ilana, ofin ẹgbẹ wa ati Nigeria. Paapaa julọ ofin ati ilana oludibo lorileede yii.

''Ẹnikẹni to ba maa jẹ oludije yoo ni anfaani lati mọ awọn oludibo, mo ni a ko rii, wọn ko fi sọwọ si wa.Awọn Pẹnkẹlẹmẹsi naa de, wọn ko pe ẹnikankan yatọ sawọn ara ọdọ yin. O daju pe ẹyin lẹ gbe wọn pamọ o.

''Ẹyin ni ẹ ko jẹ ki wọn ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe o, bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, a o tiẹ mọ, ibi taa ti fẹẹ ṣe idije lọla, o ni rara o, wọn ti gbe e sinu iwe iroyin, lo ba ni ko buru, oun a pe mi pada nigba ti yoo fi to iṣẹju mẹẹẹdogun,wọn pe pada pe awọn ti fi sọwọ si mi lori wasap, ki n lọọ wo nibẹ.

''Igba ti mo woo, mo rii, mo pe wọn pada lati dupẹ, mo ni a o ko ara wa sibẹ. Nigba to di ọjọ Satide, ọjọ Abamẹta, a ti de ibi ti wọn ti fẹẹ ṣe nnkan ni papa iṣere Onikan, ninu Mobọlaji Johnson Arena. Gbogbo wa le ni Ọgọrun- un mẹjọ, awọn ti wọn fi si ẹnu ọna, ti wọn maa ṣe ayẹwo, awọn to maa wọle, wọn ni a ko le wọle wọn ni iwe ifinihan, ti a maa mu wọle da, mo ni wọn fun wa, ọkan ninu wọn loun yoo lọ pe ọkan ninu awọn alakoso wa, lẹyin iṣẹju marun un to de lo ni nnkan ti wọn sọ ni pe eni to ni kaadi idije lọrun, nitori naa awọn ko nii jẹ ka wọle.

''Lẹyin wakati meji abọ, lẹnikan wa sọ fun wa pe ibi ta a duro si awọn ko fẹẹ wa nibẹ, ko ma ba si di aawọ, bi a ṣe kuro nibẹ."

Ṣugbọn o waa mu da wa loju pe oun nigbagbọ pe ofin yoo ṣisẹ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI