Mẹrin ninu awọn to n ba patako ipolongo idibo jẹ ni Kwara dero atimọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 12, 2022

Mẹrin ninu awọn to n ba patako ipolongo idibo jẹ ni Kwara dero atimọle


Awọn mẹrin kan ti wọn fẹsun kan pe wọn mọ nipa b'awọn tọọgi ṣe n ba papako ipolongo ẹgbẹ oṣelu jẹ kaakiri ipinlẹ Kwara ni wọn ti foju ba ile ẹjọ.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Paul Odama lo sọ eyi di mimọ f'awọn akọroyin niluu Ilọrin laipẹ yii, to si ni bọwọ ṣe tẹ wọn, loun ti lọ foju wọn ba ile ẹjọ, ko to di pe ẹnikẹni maa pe oun lori wọn.
 
Ọdama ni ko tii sẹni to pe oun lati fi wọn tu wọn silẹ, nitori pe gbogbo awọn tọwọ tẹ naa, ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ni wọn wa.
 
Nibẹ lo ti kọminu wi pe bi ipolongo idibo ṣe n fojoojumọ dagba sii, l'awọn tọọgi yii n ba patako ipolonogo ẹgbẹ oṣelu jẹ kaakiri ipinlẹ Kwara, to si l'awọn ko nii gba iwa jagidijagan laaye lakoko eto oṣelu to wa nita yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI