Mo ti lọ Washington o, mi o ni pẹẹ de - Aarẹ Buhari dagbere f'awọn ọmọ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 12, 2022

Mo ti lọ Washington o, mi o ni pẹẹ de - Aarẹ Buhari dagbere f'awọn ọmọ Naijiria


Aarẹ Muhammadu Buhari ti dagbere f'awọn ọmọ Naijiria wi pe oun n ti lọ si orileede Amẹrika, to si loun ko ni pẹẹ de pada.
 
Ibi ipade awọn olori ilẹ Amẹrika ati Afrika, eyi to fẹẹ waye niluu Washington DC ni Aarẹ Buhari kede wi pe oun n lọ.
 

Ọsan ana, tii ṣe Aiku, Sannde ni Aarẹ Buhari lọ wọ ọkọ baluu lati ipinlẹ Katsina, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
 
Ọjọ kẹtala ati ọjọ karundinlogun, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii ni ipade naa feẹ waye, eyi ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden fẹẹ fi wa oju awọn adari ilẹ Afrika.
 
A gbọ pe Aarẹ Biden fẹẹ fi ipade naa jẹ ki ibaṣepọ to wa laaarin ilẹ Amẹrika ati Afrika tubọ maa tẹsiwaju, ko si tun gbooro sii.
 

Lara awọn to tẹlẹ Aarẹ Buhari lọ ni Bala Mohammed to jẹ gomina ipinlẹ Bauchi, AbdulRahman AbdulRazaq, toun jẹ gomina ipinlẹ Kwara, awọn minisita, to fi mọ awọn agbaagba nidi eto iṣejọba Naijiria, ti wọn si lo ṣee ṣe ki wọn pada de lọjọ kejidinlogun, oṣu yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI