Aye o! Wọn ka ori oku mọ afurasi ọmọ 'Yahoo' lọwọ l'Ondo, ẹ gbọ aṣiri ohun to fẹẹ fi ṣe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 8, 2023

Aye o! Wọn ka ori oku mọ afurasi ọmọ 'Yahoo' lọwọ l'Ondo, ẹ gbọ aṣiri ohun to fẹẹ fi ṣe


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yi lọrọ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Franklin Akinyọsuyi, ẹni ti wọn sọ pe ko ni iṣẹ meji to n ṣe ju iṣẹ jibiti ori ayelujara, eyi ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo' lọ ṣi n jẹ kayeefi nla, pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe ba ori oku lọwọ ẹ.
 
Ki i ṣe bi wọn ṣe ba ori oku naa lo n jẹ kayeefi, bi ko ṣe bi wọn tun ṣe ba awọn ẹya oku miran, to fi mọ ẹjẹ eeyan ati oriṣiriṣi oogun ibilẹ abẹnugọngọ nibẹ.

B'awọn kan ṣe n sọ pe oogun owo lo fẹẹ fi ṣe, bẹẹ l'awọn kan n ni etutu aajo owo lo fẹẹ ṣe.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni awọn ọmọ kekeeke kan lo n ṣere ninu ọgba ile ti Franklin n gbe, ti wọn si kofiri ohun ajoji lẹgbẹ fẹnsi.
 
Bi awọn ọmọ naa ṣe ri i, ni wọn sare lọ ba lanlọọdu ile naa lati fi to o leti. Wọn ni baba onile naa loo pe Franklin si akiyesi, to si paṣẹ wi pe ko ṣi i, toun naa si lọra lati ṣi i.
 
Iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti wọn ba ori oku ninu baagi naa, to si mu ki baba onile gba teṣan ọlọpaa Funbi’ Fagun lọ lati fi to wọn leti wi pe ki wọn wa a wo nnkan abami toun ri ninu ọgba ile oun.

Agbegbe ti wọn pe ni Elewuro to wa niluu Ondo, ipinlẹ Ondo n'iṣẹlẹ ọhun ti waye gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
B'awọn ọlọpaa ṣe debẹ ni wọn l'awọn eeyan ti gba wọn lamọran lati lọ yẹ inu yara ti Franklin gba wo, ki wọn si le mọ iru eeyan to jẹ. Niṣe ni ariwo iyalẹnu tun sọ nigba ti wọn ba oriṣiriṣi ẹya ara eeyan, ẹjẹ ati awọn oogun ibilẹ buruku nibẹ.
 
 
Eyi lo mu ki awọn ọlọpaa gbe e lọ si teṣan lati fọrọ wa a lẹnu wo
 
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmilayọ Ọdunlami nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ ṣalaye pe baba onile ti Franklin n gbe lo lọ ta awọn ọlọpaa lolobo, ko to di pe wọn lọ ṣe iwadii.
 
Ọdunlami  sọ pe Franklin ti wa ni olu ileeṣẹ wọn, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ, to si ni idajọ ododo yoo pada waye lẹyin iwadii awọn.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI