Awọn ọdaran rugi oyin, bi ijọba Kwara ṣe pese mọto mejilelọgbọn ati aadọjọ ọkada f'awọn eleto aabo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 8, 2023

Awọn ọdaran rugi oyin, bi ijọba Kwara ṣe pese mọto mejilelọgbọn ati aadọjọ ọkada f'awọn eleto aabo


Niṣe ni ariwo ayọ sọ, ti idunnu si ṣubu lu ayọ awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara lọjọ Aje tii ṣe Mọnde ana, nigba ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fa kọkọrọ mọto mejilelọgbọn, kọkọrọ ọkada aadọjọ le awọn oṣiṣẹ eleto aabo lọwọ.

Tuntun ṣaṣa ni awọn ohun irinsẹ naa ti ijọba fa le wọn lọwọ.
 
Eyii la gbọ pe yoo mu ẹdinku ba eyikeyi iwa ọdaran to n koju ipinlẹ naa gẹgẹ bi iṣoro ati ipenija.
 
A gbọ pe kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa n'ipinlẹ Kwara ti pin awọn mọto ati ọkada naa f'awọn eleto aabo, to fi mọ awọn eleto aabo oju popona t'ipinlẹ ọhun, eyi ti a mọ si Kwara State Road Traffic Management Authority (KWARTMA).
 
Fọto:No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI